Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo ti pada kede orukọ Ọnarebu Lucky Orimisan Ayedatiwa gẹgẹ bii Adele Gomina lẹyin ti wọn ti gba lẹta, ‘mo fẹẹ lọ fun aaye isinmi’ lati ọdọ Gomina Rotimi Akeredolu.
Nigba to n tẹwọ gba lẹta ọhun lorukọ awọn ẹgbẹ rẹ, Olori awọn aṣofin ipinlẹ Ondo, Ọladiji Ọlamide, ni igbesẹ ti Arakunrin gbe wa ni ibamu pẹlu abala aadọwaa (190) ninu iwe ofin Naijiria.
O ni gẹgẹ bii ohun tí Aketi kọ sinu iwe naa, Igbakeji Gomina, Lucky Ayedatiwa, ni yoo maa dele de e titi digba ti aṣẹ mi-in yoo tun fi wa.
Aaye isinmi ti Akeredolu gba lo ni o bẹrẹ lati Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kejila, ọdun yii.
Ọladiji ni oun fi asiko naa dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ara Aketi ti n ya daadaa, bẹẹ lo ni oun gbagbọ pe Arakunrin ko ni i pẹẹ pada de lati waa maa ba iṣẹ rẹ lọ ni pẹrẹu.
Tilu tifọn ni Lucky Ayedatiwa fi wọ ilu Akurẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtala oṣu yii. Awọn alatilẹyin rẹ, to fi mọ akọwe agba tẹlẹ nipinlẹ Ondo, Ifẹdayọ Abegunde lo ki i kaabọ.