Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Pasitọ kan, Paul Ojo, ti dero ile-ẹjọ Majisreeti ilu Ado-Ekiti bayii lori ẹsun pe o lu ọmọ ijọ ẹ kan ni jibiti. O gba owo pe oun yoo ba a ṣe iwe irinna lọ siluu Dubai, ko si mu adehun ṣẹ.
Olujẹjọ, ẹni ọdun marundinlaaadọta ọhun, ni Inspẹkitọ Oriyọmi Akinwale sọ pe laarin oṣu keji si ikẹta, ọdun yii, lo huwa naa niluu Isẹ-Ekiti, pẹlu bo ṣe gba ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin (N700,000) lọwọ Fakunade Ojo.
Akinwale ni lẹyin ti pasitọ gba owo, to si ṣeleri fun Fakunade pe oun yoo ba a ṣe gbogbo eto iwe irinna naa niyẹn ko gbọ nnkan kan mọ, bẹẹ ni Paul ko da owo pada, eyi si pada di wahala laarin wọn.
Nigba to han gbangba si ẹni to kowo silẹ pe ọrọ naa ki i ṣe ere rara lo gba ọdọ awọn ọlọpaa lọ pe oun ko ri owo tabi iwe, eyi to fi han pe pasitọ oun ti lu oun ni jibiti.
Akinwale ni abala kin-in-ni ati ikẹjọ ofin to gbogun ti jibiti lilu ni olujẹjọ ṣẹ si, oun si ti fi ẹda iwe ẹsun ọhun ṣọwọ si ẹka to n gba ile-ẹjọ nimọran (DPP) ki wọn le sọ igbesẹ to kan.
O waa ni ki kootu naa sun igbẹjọ siwaju, ki wọn si fi afurasi naa pamọ sọgba ẹwọn.
Pẹlu bi ẹjọ naa ṣe lọ, ko sẹni to beere nnkan kan lọwọ pasitọ ọhun ti Majisreeti-agba Adefunmike Anoma fi ni ki wọn lọọ fi i pamọ sọgba ẹwọn, ati pe kootu naa yoo duro di igbesẹ DPP.
Igbẹjọ yoo bẹrẹ lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu yii.