Ọpẹ o, Azeez Ijaduade tawọn ọlọpaa yinbọn fun ti kuro l’ọsibitu

Adewale Adeoye

Ṣe lawọn eeyan atawọn ololufẹ gbajumọ oṣere tiata nni, Azeez Ijaduade, n da girigiri lọọ ki i nilẹ rẹ bayii ni lẹyin tawọn dokita to n ṣetọju rẹ nileewosan to ti n gba itọju tẹlẹ ti ni ko maa lọ sile pe ara rẹ ti ya.

Ọsẹ to kọja yii ni ọlọpaa kan ṣeeṣi yinbọn lu u niluu Ijẹbu-Ipẹru, nipinlẹ Ogun, tawọn ẹlẹgbẹ rẹ gbogbo si sare gbe e digba-digba lọ sileewosan awọn akẹkọọ kan to wa niluu Ijẹbu-Ode, fun itọju to peye. Ninu ọrọ rẹ lẹyin to de lati ileewosan ọhun ni gbajumọ oṣere tiata ọhun ti ṣafihan bi ọta ibọn ọlọpaa ọhun ṣe ba a lati inu mọto rẹ, to si ṣe e leṣe gidi. Bakan naa lo n dupẹ lọwọ Ọlọrun Ọba ti ko jẹ ki iku airotẹlẹ jẹ tiẹ lọdun to kọja yii.

O ni, ‘‘Fun aimọye ọjọ ni mi o fi le sọrọ lori ohun to ṣẹlẹ si mi yii rara. Emi paapaa ko mọ bi Ọlọrun Ọba ṣe ko mi yọ lọwọ iku ojiji ọhun, mo f’ọpẹ f’Ọlọrun Ọba ọga ogo ni.

‘‘Mo n fi akoko yii dupẹ gidi lọwọ gbogbo awọn ololufẹ mi pata nile loko ati lẹyin odi pe wọn ṣe e, wọn ku aduro-ti wọn lori mi, loootọ, ni adura wọn ṣiṣẹ lara mi kọja ohun ti mo ro lọ.

Ni ipari ọrọ rẹ, Ijaduade tun dupẹ gidi lọwọ awọn agba ẹgbẹ tiata ilẹ wa, ‘Theatre Arts And Motion Pictures Practitioners Association Of Nigeria’ TAMPAN fun ipa pataki ti gbogbo wọn ko lasiko to fi wa l’ọsibitu ọhun.

 

Leave a Reply