Oluṣẹyẹ Iyiade Akurẹ
Awọn tọọgi oloṣelu meje ti wọn mu ninu ọkọ ipolongo ibo ti aworan Eyitayọ Jẹgẹdẹ wa lara rẹ niluu Ifọn, nijọba ibilẹ Ọsẹ, lọsẹ to kọja, ti dero ọgba ẹwọn Olokuta to wa l’Akurẹ.
Awọn afurasi ọhun ni wọn foju bale-ẹjọ Majisreeti to wa l’ Oke-Ẹda lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, lori ẹsun biba ibọn meje pẹlu ọpọlọpọ ọta ni ikawọ wọn.
ALAROYE gbọ pe loju ọna Ikaro, niluu Ifọn, ti i ṣe ibujokoo ijọba ibilẹ Ọsẹ niṣẹlẹ naa ti waye lọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹsan-an, ọdun ta a wa yii.
Abilekọ Grace Olowopọrọku to n gbẹnu sọ fun ijọba ninu ọrọ rẹ ni ẹsun ti wọn fi kan awọn olujẹjọ naa lodi patapata si abala kẹta ninu iwe ofin orilẹ-ede yii ti ọdun 2004, eyi to ta ko ṣiṣe amulo awọn nnkan ija oloro lọna aitọ.
Agbefọba ọhun ni ki adajọ fi awọn olujẹjọ mejeeje pamọ si ọgba ẹwọn na, niwọn igba tile-ẹjọ Majisreeti ko ti lagbara labẹ ofin lati gbọ iru ẹsun ti wọn fi kan wọn.
Nigba to n gbe ipinnu rẹ kalẹ, Onidaajọ Tọpẹ Aladejana, fontẹ lu ibeere agbẹnusọ fun ijọba pẹlu bo ṣe ni kawọn afurasi janduku ọhun ṣi lọọ maa ṣere lọgba ẹwọn Olokuta titi di ọjọ kejilelogun, oṣu kẹwaa, ọdun ta a wa yii.