Esi eto idibo to waye ni Satide ọsẹ to kọja yii ti da wahala nla silẹ laarin Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ati gomina ipinlẹ Edo tẹlẹ, to tun jẹ alaga APC tẹlẹ, Adams Oshiomhole, ko si jọ pe ija to n lọ laarin awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu mejeeji yoo tan bọrọ, nitori aọn mejeeji ti kọyin sira wọn.
Inu buruku ni wọn lo n bi Asiwaju Tinubu pẹlu bi Ize-Iyamu ko ṣe wọle, ṣugbọn eyi ti wọn lo dun ọkunrin naa ju lọ ni ti Oshiomhole ti o ti ro pe o ṣi lẹnu nipinlẹ rẹ, ati pe ko ni i nira lati yege ninu ibo naa.
ALAROYE gbọ pe Oshiomhole lo lọọ ba Tinubu, to si dannu fun un pe ẹyin oun ni ọpọlọpọ awọn araalu naa wa, bẹẹ ni wọn fẹ ti Ize-Iyamu ju Obaseki lọ, gbogbo wọn lo si n leri lati ṣe atilẹyin fun ọkunrin toun fa kalẹ yii.
Ohun ti wọn lo jẹ ki oje yii jẹ Tinubu ni ti awọn ọmọ ẹgbẹ naa kan, to fi mọ awọn oloṣelu to n ba Obaseki ṣiṣẹ ti wọn kuro ninu ẹgbẹ naa, ti wọn si darapọ mọ APC. Eyi ni wọn lo ki Tinubu naa laya, to fi bọ sita, to ṣe fidio kan to ti bu Obaseki ni koṣẹ koṣẹ, nitori ọkan rẹ ti balẹ pe ẹni ti APC fa kalẹ lo maa wọle.
Ko sẹni to mọ pe ibo naa yoo lọ ni irọwọrọsẹ bo ṣe lọ yii, gbogbo ọmọ Naijiria ni wọn ti n kaya soke, ti wọn si ti ro pe oju ogun gidi ni ibo gomina to waye nipinlẹ Edo lọsẹ yii yoo da. Awọn mi-in ti n sọ asọtẹle pe oku yoo pọ, ẹjẹ yoo ṣan, afi ki ọlọmọ si kilọ fun ọmọ rẹ.
Ṣugbọn riro ni teniyan, ṣiṣẹ ni ti Ọlọrun Ọba lọrọ naa ri, ibi ti awọn eeyan ro pe eto idibo Edo yii yoo gba yọ kọ lo gba. Ba a ba ti yọwọ awọn iṣoro pẹẹpẹẹpẹ ti ko le ṣe ko ma waye lasiko eto idibo bii iru eyi, ohun gbogbo lọ nirọwọrọsẹ ni. Ko si pe a n sa ara ẹni ladaa, bẹẹ lẹnikẹni ko yọ ọbẹ sira wọn. Awọn araalu funra wọn si tete kapa awọn tọọgi ti wọn feẹ da nnkan ru, wọn o jẹ ki wọn raaye ṣiṣẹ ibi wọn.
Ọkan awọn araalu, paapaa ju lọ awọn eeyan ipinlẹ Edo ko le ṣe ko ma ko soke lori eto idibo yii, ki i ṣe ibo lasan ni wọn fẹẹ di. Ija awọn alagbara meji ni, tabi ka kuku sọ pe ija ọga ati ọmọọṣẹ ni ọrọ eto idibo to waye lọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹsan-an, yii jẹ. Ija laarin gomina ipinlẹ Edo tẹlẹ to tun figba kan jẹ alaga ẹgbẹ oṣelu APC nigba kan, Adams Aliyu Oshiomhole, ati ọmọ rẹ ninu oṣelu, toun ṣi n ṣejọba lọ gẹgẹ bii gomin l’Edo, Godwin Obaseki, ni. Baba n wa gbogbo ọna ti yoo fi fi han ọmọ rẹ yii pe kekere ni baba fi ju ọmọ lọ ko ṣee fọbẹ rẹ kuro, bẹẹ ni ọmọ naa n sọ pe baba naa ko ni i gbe oun dalẹ labẹ bo ṣe wu ko ri. Eyi lo mu ọrọ idibo naa di kankan wooko fun awọn mejeeji, ti onikaluku si n sare bi ko ṣe ni i tẹ kiri.
Ọrọ yii ki ba ma ti ri bẹẹ bi ko jẹ ija baba atọmọ to ṣẹlẹ laarin Oshiomhole ati Obaseki. Inu ẹgbẹ kan naa ni awọn mejeeji jọ wa tẹle, gomina tẹlẹ yii si wa ninu awọn ti wọn fa Obaseki kalẹ lati dupo lọdun 2016, bo tilẹ jẹ pe o ti ba a ṣiṣẹ ninu ijọba rẹ nigba toun n ṣe gomina.
Tibu tooro ipinlẹ Edo ni Oshiomhole kiri lati polongo ibo fun Obaseki ninu ẹgbẹ oṣelu APC. Pasitọ Osagie Ize-Iyamu ni awọn ẹgbẹ PDP si fa kalẹ lasiko naa lati dije. Gbogbo awọn aṣiri to dọti, ti ko ṣe e gbọ seti ti Adams mọ nipa Ize-Iyamu lo fi polongo ibo ta ko o. O si yẹyẹ ọkunrin naa debii pe ko ṣe e gba ni saara laarin awọn eeyan ipinlẹ naa.
Godwin Obaseki pada wọle ibo, ṣugbọn ọrẹ baba atọmọ yii ko tọjọ ti ija nla fi de laarin wọn. Ẹsun ti Obaseki fi kan Oshiomhole ni pe o fẹ koun maa ko owo ipinlẹ naa fun un, bẹẹ lo n rọ ọpọlọpọ awọn mọlẹbi rẹ sinu iṣejọba, eyi ti ko fun awọn eeyan mi-in lanfaani lati ri ipo oṣelu kankan di mu.
Wọn kọkọ n dọgbọn sọrọ naa, ṣugbọn nigba to ya ni sangba fọ, o si han si gbogbo aye pe tirela ti gba aarin baba atọmọ yii kọja, eku ko ke bii eku laarin wọn mọ, bẹẹ ni ẹyẹ ko ke bii ẹyẹ.
Wọn fa ọrọ naa titi, abalọ ababọ rẹ si ni bi Gomina Obaseki ṣe lo awọn kan lati da Oshiomhole duro gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ APC ni wọọdu rẹ, wọn ni awọn ti juwe ile fun un, ki i ṣọmọ ẹgbẹ awọn mọ. Eyi ti Adams iba fi tete mojuto ọrọ naa, ko si yanju rẹ, niṣe lo dagunla, to ni ko si ohun ti mẹtala wọn le ṣe fun oun.
Lile ti wọn le Oshiomhole lẹgbẹ yii ni awọn ọta rẹ kan lo ti wọn fi gbe e lọ sile-ẹjọ, wọn ni ko laṣẹ lati maa pe ara rẹ ni alaga ẹgbẹ APC mọ, nitori wọn ti yọ ọ ninu ẹgbẹ naa ni wọọdu rẹ to ti wa nipinlẹ Edo. Eyi naa ni awọn adajọ funka mọ ti wọn fi ni wọn fẹẹ yọ ọkunrin naa loye. Aarẹ Muhammadu Buhari lo gba a silẹ lakọọkọ, ṣugbọn nigba ti wọn dajọ naa to de ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun, adajọ yọ ọkunrin to ti figba kan jẹ olori ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ nilẹ wa yii nipo, wọn ni ko le ṣe alaga APC mọ. Bi ọkunrin yii ṣe sọ ẹran jọbọjọbọ nu ree, eyi gan-an lo waa fẹ ọrọ ija naa loju.
Bi adiẹ da mi loogun nu, ma fọ ọ lẹyin ni Oshiomhole fi ọrọ naa ṣe lẹyin to ja raburabu, ti ko si le pada si ipo alaga mọ. Oun naa n duro de ọmọ rẹ to yi i lagbo da sina ọhun, o ni ṣoju oun kọ ni yoo fi ṣe gomina lẹẹkeji nipinlẹ Edo. N lo ba lọọ ba alatako Ọbaseki lasiko ibo to kọja, Ize-Iyamu, o ni ko maa bọ ninu ẹgbẹ APC, awọn yoo si fun un ni tikẹẹti lati dije dupo, o si fi da a loju pe pẹlu atilẹyin oun ati ti ijọba apapọ, oun ni yoo di gomina ipinlẹ Edo lọdun yii.
Asiko idibo abẹle lati yan oludije ni wọn mu un fun Obaseki. Gbogbo ọna ni ọga rẹ si gba lati ri i pe awọn igbimọ to waa ṣeto naa ko fa a kalẹ. Wọn lọọ gbe awọn ẹsun kan kalẹ, wọn ni ko ni awọn iwe-ẹri kan, ati pe iwe-ẹri agunbanirọ rẹ ni ọwọ kan eru ninu, wọn ni orukọ rẹ yatọ. Wọn ko si fakoko ṣofo ti wọn fi sọ pe Obaseki ko le dije lati ṣoju ẹgbẹ APC ninu eto idibo to pada waye ọhun.
Ṣe bi wọn ṣe gbọn nile ọkọ naa ni wọn gbọn nile ale, o jọ pe Obaseki naa ti n ri apẹẹrẹ pe wọn ko ni i fa oun kalẹ, oun naa ti n fi ẹsẹ ẹyin dilẹ mu. Kọṣọ to ta bayii, inu ẹgbẹ PDP lo balẹ si. N lo ba di pe alatako rẹ lọdun 2016 naa lo tun fẹẹ koju, wọn kan paarọ ẹgbẹ oṣelu sira wọn ni.
Loootọ lawọn eeyan bu ẹnu atẹ lu iwa ti Oshiomhole hu yii, wọn ni ko yẹ ko ba ọmọ rẹ ninu oṣelu yii ja ija ajadiju to to bẹẹ, nitori bi wọn ko ṣe fun un ni tikẹẹti ẹgbẹ yii le ṣakoba fun aṣeyọri APC ninu eto idibo naa. Bẹẹ ni wọn bu Obaseki naa pe labẹ akoso bo ṣe wu ko ri, ko yẹ ki Obaseki huwa bẹẹ si ọga rẹ, wọn ni bii igba to ge ika to fun un lounjẹ jẹ ni pẹlu iwa to hu si ọga rẹ naa.
Ẹgbẹ awọn gomina bu ẹnu atẹ lu igbesẹ yii, awọn alẹnulọrọ naa sọ pe ki wọn lọọ pe ọkunrin naa pada, iyẹn nigba ti wọn yan igbimọ apaṣẹ tuntun lati maa tukọ ẹgbẹ naa titi ti eto idibo lati yan alaga mi-in yo fi waye. Ṣugbọn Oshiomhole ni boun yoo ṣe ṣe nnkan oun niyẹn.
Ni kete ti ẹgbẹ PDP ti fun Obaseki ni tikẹẹti lati ṣoju wọn lasiko eto idibo ọhun lo ti han pe ki i ṣe oludije ẹgbẹ APC, Ize-Iyamu, ni Obaseki fẹẹ ba dijẹ bi ko ṣe Oshiomhole funra rẹ. Eyi lo mu eto idibo to kọja naa di ija ajaku akata. Nitori ẹni to ba rẹyin ẹni keji ninu wọn ti mọ pe ẹtẹ ati abuku ti ko ni i tan nilẹ ni ẹni to ba fidi rẹmi yoo gba, ayọrisi idibo naa ni yoo si sọ ipo ti ọkọọkan wọn yoo wa nidii oṣelu.
Eyi lo fi jẹ pe gbogbo ẹmi, gbogbo ara, ni awọn mejeeji fi n ja ija naa. Nita gbangba l’Oshiomhole ti n bẹ awọn lọba lọba, bẹẹ lo n bẹ ijoye, to si ni ki gbogbo awọn toun ti ṣẹ dari gbogbo aṣiṣe oun ji oun.
Ero repẹtẹ ni ọkunrin naa lọọ ko wa lati ilu Abuja, bẹẹ lo n fojoojumọ polongo ibo kiri pe ki wọn dibo fun ẹni to fi rọpo ọmọ ẹ nidii oṣelu yii. Bi awọn alatilẹyin awọn mejeeji ṣe n polongo ibo ni wọn sọko ọrọ sira wọn, aimọye igba ni wọn si kọlu ara wọn lode, ti wọn n yọ ada yọ ọbẹ sira wọn.
Ohun to mu ki ọpọ eeyan gbagbọ pe o ṣee ṣe ki Obaseki ma rọwọ mu ni wahala to ni pẹlu awọn aṣofin, nibi ti ọpọ wọn ti kuro lẹyin rẹ, ti wọn si n wa gbogbo ọna lati yọ ọ nipo gomina ko too dọjọ ibo.
Nigba ti ibo yoo si fi ku bii ọsẹ meji, awọn eeyan ti n ya kuro lẹyin Obaseki, wọn ti n darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC. O si fẹrẹ ma si ọjọ kan ti ẹni kan ko ni i kede pe oun ti fi ẹgbẹ PDP silẹ. Nigba ti wọn yoo si fi ka a leni, eji, eeyan mejilelogoji to di ipo oṣelu kan tabi omi-in mu ti ya kuro lẹyin Obaseki, wọn ti ba Ize-Iyamu lọ. Yiya ti awọn gomina tun ya wọ ipinlẹ Edo lati ṣatilẹyin fun Ize-Iyamu fi awọn eeyan naa lọkan balẹ pe didun ni ọsan yoo so fun ẹgbẹ APC lasiko ibo ọhun.
Agbara ijọba apapọ tun wa ninu ohun ti awọn eeyan ro pe yoo ṣịṣẹ fun Oshiomhole ati ẹni to n ṣatilẹyin fun. Nigba ti okiki si kan pe awọn ọlọpaa ati ṣoja bii ẹgberun lọna ọgbọn atawọn agbofinro mi-in loriṣiiriṣii nijọba apapọ ti pese lati mojuto eto idibo naa, ko sẹni to ro pe kinni kan tun ku fun gomina to wa nibẹ naa.
Koda, gbogbo awọn to n sọrọ nipa eto idibo yii lori ẹrọ ayelujara ko tiẹ ro o lẹẹmeji ti wọn fi n sọ pe Ize-Iyamu lo maa wọle, wọn si ti bẹrẹ si i fi Obaseki ṣe yẹyẹ, oriṣiiriṣii orukọ ni wọn si n fun un. Awọn mi-in tiẹ gbagbọ pe bi ọkunrin naa wọle paapaa, ko sẹni to maa gbe ijọba fun un, nitori ẹgbẹ APC yoo ri i pe awọn dabaru gbogbo rẹ.
Ṣugbọn ko fi bẹẹ si wahala rẹpẹte lọjọ idibo yii ta a ba ti yọwọ awọn ti wọn ni wọn n pin owo ti awọn eeyan to waa dibo da sẹria fun, ati kaadi ti wọn fi n dibo ti wọn ni ko ṣiṣẹ daadaa lawọn ibi kan, eto idibo naa ko mu wahala dani rara.
Afi bi esi idibo naa ṣe gba ibi ti enikẹni ko fọkan si yọ, ti ẹkọ ko si ṣoju mimu fun ẹgbẹ APC ti wọn ti ro pe yoo rọwọ mu. Bi esi idibo naa ṣe bẹrẹ si i jade lo ti n foju han diẹ diẹ pe ọdọ awọn PDP ni esi to daa n fi si. Ṣugbọn ẹgbẹ APC ko sọ ireti nu, wọn ni nigba ti wọn ba bẹrẹ si i ka esi awọn ibi ti ẹgbẹ naa ti lagbara, gbogbo eyi ti PDP ti ni lo maa gbe mi. Ṣugbọn kaka ko san lara iya ajẹ lọrọ naa, niṣe lo n fi ọmọ rẹ bi obinrin, ti ẹyẹ wa n yi lu ẹyẹ.
Nigba ti yoo fi di aarọ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, wọn ti n ki Obaseki ku oriire, nitori awọn esi ti wọn ti ri ko jọ fi han pe yoo ṣoro ki ẹgbẹ APC too le le e ba. Ọsan Sannde lo si han gbangba pe Obaseki ti fi ẹyin baba isalẹ rẹ nidii oṣelu janlẹ, o wọ oun ati ẹni to fa kalẹ nilẹ tuurutu. Awọn ara ipinlẹ naa fi ibo wọn sọrọ, wọn ni ti ọkunrin gomina naa lawọn yoo ṣe. Lopin ohun gbogbo, ibo ẹgbẹrun lọna ọọdunrun ati meje o le diẹ (307.955) ni Obaseki ti ẹgbẹ PDP ni, Ize-Iyamu si ni ẹgbẹrun lọna igba le metalelogun ati diẹ (223, 619). Ibo ẹgbẹrun mẹrinlelọgọrin ati die ni Obaseki fi fagba han Ize-Iyamu. Ni PDP ba fi ibo gba Osihomhole wọlẹ nidii oṣelu.
Ko tun si ẹtẹ ati itiju to ju eleyii lọ fun Osihomhole, ọpọlọpọ ọna lo fi padanu, o si da bii pe esi ibo to gbe Obaseki wọle yii ti ṣegi mọ ọn lẹyin lagbo oṣelu, boya ni yoo si le dide mọ. Iya ko to iya afada pa ikun lọrọ naa si jẹ fun un, ikun lọ, ada tun sọnu. O padanu ipo alaga, ẹni to tun fa kalẹ ko wọle, eleyii to sọ ọ di alailagbara nidii oṣelu ipinlẹ ati ti Naijiria lapapọ. Pẹlu bi nnkan si ṣe ri yii, yoo feẹ to ọjọ mẹta kan ki eegun rẹ too tun ṣẹ nipinlẹ Edo. Idi ni pe ẹni ti ko ba lẹnu nile rẹ ko le maa sọrọ nita.
****Ẹni kan ti ijakulẹ ti ẹgbẹ APC tun ko itiju nla ba ni gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ, Aṣiwaju Bọla Tinubu. Yatọ si pe itiju nla ni fun un pe Oshiomhole to fi gbogbo ọjọ pọn sẹyin ja bọ, esi idibo yii paapaa ja irawọ rẹ laarin awọn ti wọn ti n ri i bii alagbara ti ko ṣe e da nidii oṣelu Naijiria.
Latigba ti ija nla ti ṣẹlẹ laarin Oshiomhole ati ọmọ rẹ to jẹ gomina Edo ni Tinubu ti n ṣatileyin fun un, oun naa lo si n sare kiri nigba ti wọn fẹẹ yọ ọkunrin naa nipo alaga ẹgbẹ APC. Ṣugbọn nitori pe ọta ile pọ ju ti ode lọ fun Adams, Tinubu ko rọna gbe e gba, afigba ti wọn fi aṣẹ ile-ejọ yọ ọkunrin naa kuro nipo alaga.
Ṣugbọn ọna kan ṣoso to gbagbọ pe ọkunrin yii fi le lẹnu ninu oṣelu Naijiria ni ko jẹ pe ẹni ti o ba fa kalẹ lo wọle ninu ibo Edo ti wọn di tan yii. Eyi lo fi mura si i kankan, to run apa ati ẹsẹ si i lati ri i pe Ize-Iyamu wọle.
Leyin to ti nawo, to tun nara, lo gbe fidio kan jade, nibi to ti sọko ọrọ si Obaseki, o si ma fẹẹ si orukọ ti ko pe ọkunrin naa ninu fidio to ṣe jade ọhun. Bẹẹ lo ni ki awọn ọmọ ipinlẹ Edo ma dibo fun un, nitori ko si ninu awọn to ja fun ijọba awa-ara-wa ti onikaluku n jẹgbadun rẹ lonii yii.
Ṣe owe Yoruba lo sọ pe oju ti ọrẹ rẹ, o ni oju ko ti ọ, tọhun ni ko lojuti, bẹẹ gẹlẹ lọrọ ri fun Tinubu ati Oshiomhole, nitori itiju to ba a naa lo ba ọga rẹ nidii oṣelu. Awọn ara Edo jọ fi ibo ti wọn di naa wọ wọn nile tuurutu ni.
Ka ni Ize-Iyamu wọle ni, kẹnkẹ bayii ni iyi rẹ iba to laarin awọn oloselu ẹgbẹ rẹ gbogbo. Koda, wọn iba maa bọwọ fun un ju Aarẹ Buhari to n ṣakoso orileede yii gan-an lọ. Ṣugbọn ẹkọ ko ṣoju mumu fun wọn. Ijakulẹ ti wọn ko lero ni wọn ba pade.
Obaseki naa ti sọrọ, o ki gbogbo awọn ara Edo ku oriire, o ni oun dupẹ bi wọn ṣe ti oun lẹyin, ti awọn si jọ fopin si oṣelu baba isalẹ, oṣelu ‘baba sọ pe’. Bẹẹ lawọn eeyan ni fi Ize-Iyamu, Oshiomhole ati Bọla Tinubu to bu Obaseki labuṣidii lasiko ti ọjọ ibo ku fẹẹrẹfẹ ṣe yẹyẹ, wọn ni Ọlọrun ju wọn lọ.
Ize-Iyamu naa ti sọrọ. O ni ki awọn ololufẹ ati alatilẹyin oun ni suuru, ki wọn ma si bọkan jẹ. Ọkunrin yii ni oun ti n ṣagbeyewo bi gbogbo eto idibo naa ṣe lọ, oun yoo si gbe igbesẹ to ba yẹ lori abajade esi idibo naa laipẹ rara.
Ireti awọn eeyan ni pe bi awo ba ki fun ni, o di dandan ki tọhun naa ki pada fun un. Wọn ni pẹlu atileyin ti Obaseki ri gba lọwọ awọn eeyan ipinle Edo yii, awọn eto ati iṣẹ ti yoo mu ayipada rere ba ipinle naa atawọn eeyan Edo lapapọ lo yẹ ko gun le. Bakan naa ni Aarẹ Buhari ti ki i ku oriire bo ṣe wọle lẹẹkeji yii.