Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ile-ẹjọ Majisreeti kan to wa l’Ado-Ekiti, ti paṣẹ pe ki okunrin ẹni ọdun marunlelogoji kan, Tajudeen Olalẹyẹ, maa lọọ gbatẹgun lọgba ẹwọn lori ẹsun pe o pa obinrin to n la oun atẹni to jọ n ja.
Agbefọba, Insipẹkitọ Yọmi Oṣunọlale, ṣalaye ni kootu pe ọdaran naa ṣe ẹsẹ yii lọjọ kẹwaa, oṣu Kẹta, ọdun 2024, ni Ọtun -Ekiti, nijọba ibilẹ Moba, nipinlẹ Ekiti.
O ṣalaye pe ọdaran naa pa obinrin ẹni ogoji ọdun kan, Arabinrin Taibat Rasaki, to jẹ araadugbo wọn lakooko tiyẹn n laja laarin oun ati ẹnikan ti wọn jọ n ja. Igo ni wọn lo fi gun un.
Agbefọba ni eṣe yii lodi sofin ipaniyan ti ipinlẹ Ekiti, ti wọn kọ lọdun 2012. O waa rọ ile-ẹjọ pe ko fi ọdaran naa pamọ sọgba ẹwọn titi di akoko ti imọran yoo fi wa lati ọdọ ijọba. Bakan naa lo ṣalaye pe oun ṣetan lati pe ẹlẹrii wa sile-ẹjọ naa lati waa jẹrii lori ọrọ ọhun.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Olubunmi Bamidele, paṣẹ pe ki ọdaran naa maa lọ sọgba ẹwọn titi di ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2024, ti ẹjọ naa yoo maa tẹsiwaju.