Adewale Adeoye
Ọgbẹni Steady Munda ti n kawọ pọnyin rojọ lagọọ ọlọpaa kan to wa ni agbegbe Chemowa, lorileede Zimbabwe, wọn lo pa ọmọ rẹ, ọmọọdun mẹta, sinu igbo lati fi ṣoogun owo.
ALAROYE gbọ pe ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, ni Ọgbẹni Steady huwa naa. Loju-ẹsẹ to pa ọmọ ọhun tan sinu igbo lo ti yọ awọn ẹya ara rẹ kan to fẹẹ lo, o si ju iyooku ara ọmọ ọhun sinu odo to n ṣan lagbegbe naa. Ṣa o, ọwọ ọlọpaa pada tẹ ẹ, ti wọn si ti fọwọ ofin mu un.
Nigba ti awọn agbofinro n fọrọ wa a lẹnu wo lo jẹwọ pe loootọ, oun loun pa ọmọ oun ti ko ju ọmọọdun mẹta lọ naa lati fi ṣoogun owo, nitori ilu le e gidi foun.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe ZRP Gokwe, Insipẹkitọ Emmanuel Mahoko, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹta, ọdun yii, sọ pe ọdọ awọn ni Steady wa bayii to n ran awọn lọwọ lori iwadii awọn lati le fọwọ ofin mu Ọgbẹni Ttambu toun ati Steady fẹẹ fọmọ ọhun soogun owo.
Atẹjade kan ti wọn fi sita lori iṣẹlẹ ọhun lọ bayii pe, ‘Lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni Steady ati ọrẹ rẹ kan, Ọgbẹni Daston Mucheuki, n lọ sagbegbe Chemowa, nileewe ọmọ rẹ lati lọọ ṣiṣe kan nibẹ. Steady mu ọmọ rẹ, ọmọ ọdun mẹta dani. Lasiko ti wọn n lọ lọna ni mọto akero ti wọn wa ninu rẹ bajẹ soju titi, bi awọn ero inu mọto ọhun ṣe bọ silẹ ni Steady ti poora pẹlu ọmọ rẹ, to si sa wọnu igbo kan lọ. Ọrẹ rẹ atawọn kan bẹrẹ si i wa a kiri, nitori to n ṣe wọn ni kaayefi pe wọn ko mọ ibi to wa pẹlu ọmọ ọwọ rẹ.
Awọn akẹkọọ ileewe kan ti wọn ri Steady ati ọmọ rẹ lẹgbẹẹ odo ni wọn waa sọ fawọn to n wa a pe eti odo lo wa, nigba tawọn ero ọhun maa fi de ibi to wa, Steady ti gbẹmi ọmọ ọhun, o si ti ju oku rẹ sinu odo. Wọn kan sawọn ọlọpaa agbegbe naa, tawọn yẹn si tete fọwọ ofin mu un lọ sọdọ wọn.
Awọn ọlọpaa ti sọ pe awọn n ṣiṣẹ takuntakun labẹnu bayii lati fọwọ ofin mu ọrẹ Steady ti ọdaran ọhun darukọ pe awọn jọ fẹẹ lo ọmọ naa fi ṣoogun owo ni.