Arun korona kọlu olori Amẹrika ati iyawo ẹ

Aderounmu Kazeem

Bi eto idibo ilẹ America ṣe n sunmọ, ti ipolongo ibo n lọ kikankikan, Aarẹ orilẹ-ede naa, Donald Trump, ti lugbadi arun koronafairọọsi pẹlu iyawo ẹ bayii o.

Loni-in, Fraidee, ọjọ Ẹti ni iroyin ọhun jade. Ohun ti dọkita ẹ si sọ ni pe, ki i ṣe pe arun koronafairọọsi naa ti da a dubulẹ, Trump ṣi le maa ba iṣẹ ẹ lọ bo ti ṣe wa ni ipamọ fun itọju ninu ile ijọba, White House.

Ki i ṣe Trump nikan ni arun yii kọlu, wọn loun ati iyawo ẹ, Melania, ni wọn jọ ko o. Bẹẹ lawọn eeyan kan ninu awọn oṣisẹ naa ti wa ninu wahala ọhun.

Pẹlu wahala ti Aarẹ ilẹ Amerika ko si yii, awọn eeyan kan ti n sọ pe, bawo lo ṣe fẹẹ ṣe e pelu bi ọjọ idibo ṣe ju ku ọjọ mejilelọgbọn, paapaa bo ti ṣe ni awọn eto ipolongo ibo kaakiri ilẹ Amẹrika.

Ṣaaju asiko yii ni alatako ẹ, ẹni ti wọn jọ n dije dupo aarẹ,  Joe Biden ti ẹgbẹ oṣelu Democrat ti bu ẹnu atẹ lu bi Trump ṣe n ko ọpọ ero jọ fun ipolongo ibo, ti ko si naani wahala arun koronafairọọsi to gba ode agbaye kan.

Ni bayii, wọn ti ni yoo ṣoro fun un lati tẹ siwaju pẹlu awọn eto to ti ni silẹ fun ipolongo ibo ẹ, nitori o ṣe pataki ki o wa ni igbele, bẹẹ gẹgẹ niyawo ẹ naa, ti wọn jọ lugbadi arun buruku yii.

 

 

Leave a Reply