Awọn eleyii yoo pẹ lẹwọn o, agbẹ kan ni wọn pa sinu oko rẹ ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ile-ẹjọ Majisireeti kan to filu Ilọrin nipinlẹ Kwara, ṣebujokoo ti paṣẹ pe ki wọn lọọ ju awọn afurasi meji kan, Ṣẹgun Ọbatunlese ati Ṣọla Ajayi, sahaamọ ọgba ẹwọn titi ti igbẹjọ yoo fi waye lori ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan wọn. Agbẹ kan, Ọgbẹni Wasiu Jimoh, ni wọn pa sinu oko kaṣu rẹ nijọba ibilẹ Ìsin, nipinlẹ naa, leyi ti wọn ni o ta ko abala kẹtadinlọgọrun-un ninu iwe ofin ilẹ wa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni Kwara, lo wọ awọn afurasi ọhun lọ siwaju ile-ẹjọ lati waa ṣalaye ara wọn lori ẹsun ipaniyan ati igbimọ pọ ti wọn fi kan wọn ọhun.

Agbefọba, Mathew Ọlọgbọnsaye, sọ fun ile-ẹjọ pe ọkunrin agbẹ ti wọn pa yii ba awọn ọkunrin meje kan ninu oko kaṣu rẹ ti wọn n ji koro kaṣu, nitori pe ọkunrin yii ka wọn mọ’bi iṣẹ buruku ti wọn n ṣe ọhun ni mẹta ninu wọn ṣe bẹrẹ si i fi ada le ọkunrin agbẹ naa kiri, ti wọn si fi ada ṣa a wẹlẹwẹlẹ, wọn tun yinbọn lu u, leyii to mu ko padanu ẹmi rẹ sibi iṣẹlẹ naa.

O tẹsiwaju pe ni kete ti iwadii bẹrẹ ni ọwọ ọlọpaa tẹ awọn afurasi mejeeji yii, ti Ọbatunlese si jẹwọ pe Ajayi lo pe oun lori foonu pe ole kan n le oun ninu oko, ti ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Ahmed, ti ibọn wa lọwọ rẹ si yinbọn si Jimoh ninu oko kaṣu, ṣugbọn awọn ko mọ pe irọ ni Ajayi n pa. Bayii ni ọkunrin agbẹ naa ṣe ku iku gbigbona.

Agbefọba Mathew rọ ile-ẹjọ ki fi awọn afurasi naa sahaamọ ọgba ẹwọn titi ti iwadii yoo fi pari lori ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan wọn.

Adajọ F B Saliu paṣẹ ki wọn lọọ ju wọn sahaamọ ọgba ẹwọn titi igbẹjọ yoo fi waye lori ẹsun ọdaran ti wọn fi kan wọn.

 

Leave a Reply