Adewale Adeoye
Ọdọ awọn ọlọpaa agbegbe Bomadi, nijọba ibilẹ Bomadi, nipinlẹ Delta, ni baale ile kan, Ọgbẹni Chinemem Adigwe, to n pọn ọti ayederu laarin ilu wa bayii, o n ran wọn lọwọ ninu iwadii wọn nipa ẹsun ti wọn fi kan an.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, ni ọwọ awọn agbofinro tẹ ẹ lasiko to n pọn ọti ayederu naa sinu igo to jẹ ojulowo, to si n ta a fawọn araalu lowo nla.
ALAROYE gbọ pe o ti pẹ ti afurasi ọdaran ọhun ti n ṣisẹ laabi ọhun. Awọn ọti lile bii: Chelsea, Mc Dowel ati Gordon’s ni ọkunrin naa maa n pọn ta.
Awọn araalu kan ti wọn mọ nipa iṣẹ to lodi sofin to n ṣe yii ni wọn lọọ fọrọ rẹ to awọn ọlọpaa agbegbe naa leti, tawọn yẹn si lọọ fọwọ ofin mu un.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, S.P Bright Edafe, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun yii, sọ pe loootọ, ọdọ awọn ni Adigwe wa bayii, o n ran awọn agbofinro lọwọ ninu iwadii wọn.
Atẹjade kan ti wọn fi sita lori iṣẹlẹ ọhun ni wọn ti kilọ faọn araalu paapaa ju lọ awọn to n mu ọti lile bii: Chelsea, Mc Dowel ati Gordon’s, pe ki wọn ṣọra ti wọn ba fẹẹ mu ọti ọhun bayii, nitori ayederu ọti naa ti pọ daadaa nita. ‘‘Ọgbẹni Adigwe, la ṣẹṣẹ fọwọ ofin mu laipẹ yii, o maa n pọn ọti ayederu laarin ilu, kẹmika ati omi lasan lo maa n da papọ, aa lọọ ra igo ofifo lọja, yoo si rọ ọ sinu rẹ, ti o si n ta a fawọn araalu lowo nla. Awọn ayederu ọti wọnyi ki i ṣe ohun to daa lati maa mu, akoba nla lo maa n fa fun ilera awọn eeyan.
Alukoro ni awọn maa too foju Adigwe bale-ẹjọ laipẹ yii, ko le fimu kata ofin fohun to ṣe.