O ma waa ga o, eeyan mọkandinlogun tun jona gburugburu ninu ijamba ọkọ ni Kogi

Faith Adebọla

 Leyii ti ko ti i ju ọsẹ kan lọ tawọn eeyan mẹẹẹdọgbọn kan jona ku sinu ijamba ọkọ nipinlẹ Kogi, o kere tan, eeyan mọkandinlogun ni wọn ti tun fidi rẹ mulẹ pe wọn ku iku gbigbona, iku oro, ni wọn jona gburugburu lasiko ti ijamba ọkọ kan waye nirọlẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejidinlọgbọn, ọsu Kẹrin, ọdun 2024 yii.

Oludari ẹka eto iroyin fun ajọ awọn ẹṣọ alaabo loju popo, Federal Road Safety Commission (FRSC), nipinlẹ Kogi, Ọgbẹni Jonas Agwu, fidi ẹ mulẹ pe ijamba buruku ọhun waye nigba ti ọkọ ajagbe ti ileeṣẹ Dangote Cement kan ati bọọsi Toyota Hiace fori sọ ara wọn lagbegbe Okene Bypass, to wa lọna marosẹ Okene si Lọkọja, nipinlẹ ọhun.

Agwu ni fun bii wakati mẹta lawọn oṣiṣẹ Road Safety fi ja fitafita lati doola ẹmi awọn eeyan naa, amọ ina ọmọ ọrara to bẹ silẹ nigba ti ijamba naa waye kọja bẹẹ, gbogbo ero to si wa ninu bọọsi akero Hiace naa lo jona patapata.

O ṣalaye siwaju si i pe lati ipinlẹ Kano ni bọọsi akero naa ti n bọ, oju ọna to yẹ ko tọ lo si wa, tirela Dangote lo fi ọna tirẹ silẹ pẹlu ere buruku, to lọọ ya ba bọọsi naa, ati pe bawọn mejeeji ṣe fori sọ ara wọn lagbara gidi debii pe niṣe ni ina ṣẹ yọ, ti bẹntiroolu si mu ki ina naa fẹju kankan.

Gende mejilelogun ni ijamba naa ka mọ, amọ mọkandinlogun ninu wọn gbabẹ sọda, ina jo wọn pa, nigba tawọn mẹta yooku fara gbọgbẹ yanna-yanna, ti isapa ṣi n lọ lati doola ẹmi wọn.

Atẹjade Road Safety ni ohun to tubọ mu kawọn meji ribi mori b ni pe wọn lo bẹliiti to yẹ kawọn ti wọn jokoo siwaju ọkọ fi de ara wọn (seat belt), o leyii lori fi ko wọn yọ.

O tun ni iwadii akọkọ tawọn ṣe fihan pe yiya ara ẹni silẹ lori ere lọna ti ko yẹ tawọn ọkọ yii ya ara wọn, iyẹn (wrongful overtaking) lede oyinbo, lo ṣokunfa ijamba gbẹmi-gbẹmi yii.

O lawọn ti ko ajoku oku awọn ero naa lọ si mọṣuari ọsibitu ijọba to wa l’Okene, iyẹn Okene General Hospital.

Bakan naa lo lawọn ri dẹrẹba to wa tirela naa mu, iwadii si ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ yii. Agwu lawọn maa foju awakọ yii bale-ẹjọ lẹyin iwadii.

Ẹ oo ranti pe ko ti i ju ọsẹ kan lọ, iyẹn lọjọ Aiku, Sannde, to ṣaaju eyi, tawọn eeyan mẹẹẹdọgbọn kan padanu ẹmi wọn sinu ijamba ọkọ nipinlẹ Kogi yii kan naa. Niṣe ni ina jo awọn naa pa, nigba ti ọkọ Toyota Sienna kan pẹlu bọọsi Toyota Hiace kan fori sọra pẹlu tirela kan.

A gbọ pe koto nla kan to wa lọna ọhun, niwaju ileewe ẹkọṣẹ tiṣa, Aloma Teachers College, ni Aloma, nijọba ibilẹ Ofu, lo ṣokunfa ijamba to la ina buruku lọ ọhun.

Leave a Reply