Monisọla Saka
Awọn eeyan bii mẹrindinlogun ni wọn ti ṣe bẹẹ gbọna ọrun lọ nibi ijamba ọkọ kan to waye loju ọna Enugu/Opi si Nsukka, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọgbọnjọ, oṣu Kẹrin, ọdun yii.
Awọn ọkunrin mẹrinla ati obinrin meji, ni wọn wa ninu ọkọ akero to lọọ fori sọ fẹnsi Fasiti Maduka, to si ṣe bẹẹ gbina lojiji.
Daniel Ndukwe, ti i ṣe agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Enugu, lo sọrọ yii di mimọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Karun-un, ọdun yii.
O ni ọkọ akero elero mejidinlogun ti nọmba rẹ jẹ DAS 215 XA, to jẹ tipinlẹ Bauchi, lo lọọ rọ lu fẹnsi Maduka University, lojiji, ti ina si sọ.
Ere asapajude ni Ndukwe sọ pe o ṣokunfa bi ọkọ ọhun ṣe sọ ijanu ẹ nu, to fi rọ lu fẹnsi naa, ti ina di sọ lojiji, to si gbẹmi awọn eeyan mẹrindinlogun naa, ti wọn si ri eeyan meji doola.
O ni, “Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Enugu n fi akoko yii fi to awọn araalu leti pe ijamba ọkọ kan to waye ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ kọja ogun iṣẹju, lọgbọnjọ, oṣu Kẹrin, ọdun yii, lagbegbe Ekwegbe, oju ọna Enugu/Opi si Nsukka, ti mu ẹmi eeyan mẹrindinlogun, ọkunrin mẹrinla ati obinrin meji, ti wọn jona kọja idanimọ lọ.
‘’Awọn nnkan bii ounjẹ loriṣiiriṣii, ẹfọ ati ẹru awọn ero inu ọkọ lo kun inu mọto to n lọ si ọna Nsukka lati Enugu yii, amọ to jẹ pe ko sẹni to le sọ ibi ti wọn ti gbera ati ibi to n lọ gan-an ni pato’’.
Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ naa, CP Kanayo Uzuegbu ti rọ awọn araalu lati yọju, ki wọn le tọka si ẹni wọn tabi ki wọn ran wọn lọwọ lati wa awọn mọlẹbi oloogbe kan.