Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ti gboriyin fun Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, fun bo ṣe mojuto biriiji nla kan to n ṣediwọ fun iṣẹ oju-ọna Ibadan si Iwo.
Biriiji ọhun to wa lagbegbe Olodo, niluu Ibadan, ni Ọba Akanbi sọ pe ko si lara ohun ti awọn agbaṣẹṣe kọ fun awọn gomina ipinlẹ Ọyọ ati ti Ọṣun.
O ni nigba ti iṣẹ debẹ lawọn kọngila ri i pe bi wọn ba fi biriiji naa silẹ ni kẹjẹbu to wa tẹlẹ, o le fa idiwọ fun aṣeyọri oju ọna naa.
Lasiko ti Ọba Akanbi ṣabẹwo si biriiji ọhun lo fi idunnu rẹ han lorii bi Gomina Makinde ṣe pakiti mọlẹ, to si yọnda owo fun biriiji nla naa.
O ni ohun to jẹ ko ya oun lẹnu ni pe gomina ko wa saa kẹta, o ti lo saa akọkọ, o si ti n lo saa keji lọ, to ba lo owo to n na lori biriiji naa lọwọlọwọ lori nnkan mi-in, ko sẹni to le mu un.
Ọba Akanbi waa ke si gomina ipinlẹ Ọyọ ati ti Ọṣun, lati tete yọnda owo fun aṣeyọri oju-ọna naa, o ni ọna Ibadan si Iwo ṣe pataki fun eto ọrọ-aje ipinlẹ mejeeji.
Ninu ọrọ ọkan lara awọn olugbe Olodo, Ọgbẹni Thomas Adekanmi, dupẹ lọwọ awọn gomlna ipinlẹ mejeeji fun ifọwọsowọpọ wọn lori atunṣe oju-ọna ọhun.
O ni biriiji Olodo naa jẹ ọkan lara ibi to maa n fun awọn eeyan ni idaamu pupọ nigbakuugba ti ojo ba ti rọ, ṣugbọn ni bayii ti wọn ti ṣe e, ifọkanbalẹ ti wa fawọn olugbe Olodo.
Bakan naa lo dupẹ lọwọ Ọba Adewale Akanbi fun bo ṣe ṣe ọrọ atunṣe oju-ọna naa ni igbin- tẹnu-mọgi, o gun un.