Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ẹwọn ọdun mẹrin ni adajọ ile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Oṣogbo, ju Fulani darandaran kan, Mohamodu Zuberu, ọmọ ọdun mejilelogun, si lori ẹsun ijinigbe.
Ọmọkunrin yii ni wọn fẹsun kan pe o ji ọmọ ọdun mẹtala kan, Tunde Abdullahi, gbe labule Iwari, to wa niluu Ikoyi.
Ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹjọ, ọdun yii, la gbọ pe Zuberu ji ọmọ naa gbe laarin oru, to si gbe e pamọ si ibi ti ẹnikẹni ko mọ. Miliọnu meji naira lo kọkọ n beere lọwọ awọn mọlẹbi Tunde, nigba to ya lo sọ ọ di ẹgbẹrun lọna ọtalelọọdunrun-un o din mẹwaa naira (#350,000).
Ni gbogbo asiko yii lawọn ọlọpaa n dọdẹ Zuberu ko too di pe ọwọ tẹ ẹ. Ọjọ kẹta, oṣu kẹsan-an, ọdun yii, lo kọkọ fara han nile-ẹjọ lori ẹsun ijinigbe, adajọ si mu ọsẹ to kọja lati ṣedajọ rẹ.
Ni kootu, Zuberu, ẹni ti ko ni agbẹjọro kankan to n duro fun un sọ pe oun jẹbi ẹsun ijinigbe ti awọn ọlọpaa fi kan oun.
Lara awọn ẹri ti awọn ọlọpaa ko wa sile-ẹjọ lati fi gbe ẹsun yii lẹsẹ ni tọọsi, foonu ati aṣọ-oorun (pull-over) ti Zuberu n lo nibi to gbe Tunde pamọ si.
Lẹyin ti Adajọ Ọpẹyẹmi Badmus gbọ atotonu awọn ọlọpaa ati bi olujẹjọ ṣe ti gba pe oun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an, o paṣẹ pe ki Zuberu lọọ fi aṣọ-penpe roko ọba lọgba ẹwọn to wa niluu Ileṣa fun ọdun mẹrin gbako.