O ma ṣe o! Eeyan meji ku nibi tanka epo to gbina l’Ekoo

 Monisọla Saka

Eeyan meji lo ti ṣe bẹẹ pade iku ojiji, lasiko ti tanka epo kan gbina lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Karun-un, ọdun yii, lori biriiji to lọ si Ijẹsha lati Cele, Surulere, nipinlẹ Eko.

Ni nnkan bii aago mọkanla alẹ kọja iṣẹju mejila, ni wọn ni iṣẹlẹ laabi yii waye, lasiko ti awakọ tanka epo naa sọ ijanu ọkọ nu nigba to fẹẹ yi kọna lati sọ kalẹ biriiji naa.

Epo to yi danu yii ni wọn lo gbina lojiji, ti eefin dudu si bo gbogbo agbegbe naa pitimu. Amọ o ṣe ni laaanu pe gende-kunrin meji ti ina jo kọja ki wọn da wọn mọ ni wọn ba iṣẹlẹ naa lọ.

Ninu atẹjade ti Arabinrin Margaret Adeṣẹyẹ, ti i ṣe adari ileeṣẹ panapana nipinlẹ Eko fi sita lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanla, oṣu Karun-un, ọdun yii, lo ti ṣalaye pe lẹyẹ-o-sọka lawọn oṣiṣẹ panapana yọju sibi iṣẹlẹ ijamba ina naa.

“Ni deede aago mọkanla alẹ kọja iṣẹju mejila ni wọn pe ileeṣẹ panapana nipe pajawiri pe ọkọ tanka kan to gbe epo bẹntiroolu oni jálá ẹgbẹrun mẹtalelọgbọn (33,000 litres), sọ ijanu rẹ nu nibi kọna ti yoo fi da firi biriiji sọkalẹ. Eyi lo ṣokunfa bi epo to gbe ṣe danu, to si gbina lẹsẹ kan naa.

“Ileeṣẹ panapana Isọlọ ati ti Bọlade ti wọn tete de sibi iṣẹlẹ naa, ti wọn si pa a lo dena ina ajoran ti iba ṣẹlẹ.

Oku awọn eeyan meji ti wọn ri ni wọn ti fa le awọn agbofinro lọwọ fun gbogbo eto to ba yẹ.

Bakan naa ni ileeṣẹ to n mojuto itọju pajawiri nipinlẹ Eko, Lagos State Ambulance Service, naa kun wa lọwọ titi ti a fi pari gbogbo iṣẹ naa”.

O ṣalaye siwaju si i pe gbogbo akitiyan lawọn n ṣe lati palẹ ajoku ọkọ ati gbogbo wosiwosi to wa oju popo mọ, ko ma baa ṣokunfa sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ fawọn mọto oju popo.

 

Leave a Reply