Idajọ oju-ẹsẹ: Wọn mu’na wa lojiji nibi ti Sunday atawọn ẹgbẹ ẹ ti n ji tiransifọma tu l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọmọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlogun kan to p’orukọ ara rẹ ni, Sunday Adegbulu ni ina jo apa kan ara rẹ gburu gburu lasiko ti oun atawọn ẹmẹwa rẹ kan n ji tiransifọma ina tu l’Akurẹ.

Ọmọkunrin ọhun lo wa lara awọn afusrasi ọdaran marundinlaaadọta ti awọn ẹṣọ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo ṣafihan wọn fawọn oniroyin lolu ileeṣẹ wọn to wa ni Alagbaka, niluu Akurẹ, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtala, oṣu Karun-un, ọdun 2024 ta a wa ninu rẹ yii.

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ, Alakooso ẹsọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Oloye Adetunji Adelẹyẹ, ni ọjọ pẹ ti Sunday atawọn ọmọ ẹgbẹ rẹ ninu ole jija ti wa lẹnu iṣẹ ibi ti wọn n ṣe naa ki wọn too ṣe eyi to bu wọn lọwọ laipẹ yii, ti ọwọ si tẹ ọkan ninu wọn.

Adelẹyẹ ni awọn waya olowo nla to gbe ina wọnu awọn tiransifọma ọhun ni Sunday n ge lọwọ ti ina fi de lojiji, to si jo apa kan ara rẹ lati oke delẹ.

O ni kiakia lẹyin iṣẹlẹ ọhun lawọn ojugba rẹ yooku ti tete gbe e lọ si ọsibitu kan lati lọọ tọju rẹ, ṣugbọn ti wọn tun sare gbe e kuro nibẹ nigba ti wọn fura pe awọn ẹṣọ Amọtẹkun ti n tọ paṣẹ awọn.

Adelẹyẹ ni ileewosan kẹta ti wọn gbe ọmọkunrin yii lọ lọwọ awọn ti pada tẹ ẹ, ti awọn funra awọn si ṣẹṣẹ waa gbe e lọ si ọsibitu gidi, nibi ti wọn ti tọju rẹ titi ti ara rẹ fi ya.

Ọkunrin yii ni ṣe lawọn ẹgbẹ ẹ mọ-ọn-mọ fẹẹ pa a ki aṣiri wọn ma baa tu si awọn agbofinro lọwọ.

Oloye Adelẹyẹ ni eeyan mẹsan-an ni Sunday ti ka orukọ wọn pe ṣe lawọn jọ n ṣiṣẹ ibi naa, bẹẹ lo darukọ baba-isalẹ wọn. Ẹni to jẹ baba isalẹ awọn a-lọ-kolohun-kigbe naa lo ni awọn ti n dọdẹ rẹ, ti awọn ko si ni i sinmi ti ti tọwọ yoo fi pada tẹ ẹ.

Eyi ni ọrọ diẹ ti Sunday ba ALAROYE sọ nigba ta a n fọrọ wa a lẹnu wo :

‘’Sunday Adegbulu ni orukọ mi, ọmọ ọdun mẹtadinlogun ni mi, kilaasi kẹta akọkọ (JSS 3) ni mo wa nileewe girama Commercial, to wa l’Akurẹ.

Awa mẹta la jọ n jale, waya ina la si yan laayo ti a maa n tu yala ninu ile tí wọn ba n kọ lọwọ tabi lara ẹrọ amunawa. Ẹgbẹrun mẹẹẹdọgbọn Naira la fẹẹ ta eyi ta a lọọ tu kẹyin fun baba isalẹ wa to n jẹ Ọgbẹni Abubakar.

‘‘Ẹẹkeji ti ma a ba wọn lọ soko ole lọwọ palaba mi ṣegi, akọkọ ti mo ba wọn lọ, waya ina ile akọku kan la jọ lọọ ji ka.

‘’Ni ti ẹlẹẹkeji yii, emi o tilẹ ro pe wọn le mu ina wa bẹẹ rara, ibi ti mo bẹrẹ mọlẹ si ti mo ti n ge waya ni ina ti de lojiji, to si jo apa kan ara mi, mo fẹ ki ijọba saanu mi, nitori eṣu lo ti mi’’.

Leave a Reply