O tan, Portable ti wa latimọle ọlọpaa  

Jọkẹ Amọri

Ọrọ naa ti di ẹgbẹrun Saamu ti ko le sa mọ Ọlọrun lọwọ bayii pẹlu bi wọn ti ṣe gba Habib Ọlalọmi ti gbogbo eeyan mọ si Portable mu, to si ti wa ni galagala awọn ọlọpaa lasiko ta a n ko iroyin yii jọ.

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrinla, oṣu yii, ni awọn agbofinro lọọ ka Portable mọ ibi to wa, ṣe wọn kuku ti n ṣọ ọ toun ko mọ, ni wọn ba pagbo yi i ka, wọn si mu iwe aṣẹ ti wọn gba lati mu un iyẹn (warrant of arrest) jade, ti wọn fi han an pe awọn waa mu un.

Bawọn ọlọpaa ṣe ka a mọ kọna nibi ile kan ni wọn ni, ‘‘Portable, iwọ la waa mu, iwe aṣẹ ti wọn si fun wa lati mu ẹ niyi’’.

Ni oṣere yii ba bẹrẹ si i pooyi bii ṣia baaba, bo ṣe n lọ lo n bọ, to si n sọ pe, ‘Mọto naa ni eleyii, mọto naa niyi, mọto naa niyẹn. Gbogbo bo ba ṣe jẹ, mo maa ku sibi loni’. Bẹẹ lo n sọ fawọn ọlọpaa to waa mu un pe oun n bọ, nigba ti awọn yẹn ni awọn waa mu un.

Afi bo ṣe fẹyin rin lọ sibi ẹyinkule geeti kan to wa nitosi ibi ti wọn ti n ba a sọrọ, ki awọn to wa nibẹ si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, ọmọkunrin olorin ti ẹnu ki i sin lara rẹ naa ti bẹ gija bii ologbo sori geeti giga kan to wa nibi ti wọn ti n ba a sọrọ, n ni ẹlẹgiri ba ta kọsọ si odi-keji. Ọlọrun lo si yọ ọmọ Ọlalọmi ti baba ọmọ rẹ ko gun irin geeti, nitori to ba ṣẹlẹ bẹẹ ni, ọtọ ni ohun ti a ba maa wi bayii. Afi bii fiimu agbelewo ni ọrọ naa ri fun gbogbo awọn to wa nibẹ, to fi mọ awọn ọlọpaa to waa mu un. Ohun ti awọn kan si n wi ni pe aṣe Portable ko tiẹ le, ẹnu lo ni bii ti ajakara.

Ṣugbọn niṣe ni ọpọ eeyan ro pe Portable ti sa mọ awọn ọlọpaa lọwọ. Afi bi wọn ṣe lọọ gba ọna odi keji, ti wọn si rẹburuu ọmọkunrin to maa n pe ara rẹ ni Ika of Afrika tabi Idaamu adugbo yii.

Ṣugbọn Portable ko ri awọn ọlọpaa daamu nigba ti wọn gba a mu, awọn agbofinro ni wọn daamu rẹ, nitori niṣe ni wọn n wọ ọ nilẹ tuuru. Iran dun un wo nigba ti wọn n gbe ọmọkunrin olori yii. Bi awọn agbofinro ṣe n gbiyanju ati gbe e lo n pariwo, to si n na tọtọ bii ọpọlọ ti wọn ju sinu omi gbigbona. Awọn agbofinro bii mẹrin ni wọn ṣuru bo o bii igba ti eera ba bo ṣuga, ni wọn ba gbe olorin Zah zu ze ni papanyaka, ṣugbọn bi wọn ṣe n gbe e lo n na watiwati, ko si fẹ ki wọn ri oun gbe.

Niṣe ni obinrin to gbe mọto fun Portable, to si lọọ fọlọpaa mu un yii bẹrẹ si i sọ fun un pe ko fẹsọ wọle sinu mọto tawọn ọlọpaa gbe wa lati waa gbe e, ko ma baa ṣe ara rẹ leṣe, ṣugbọn Portable ṣaa n lo gbogbo agbara lati ri i pe wọn ko ri oun gbe ni, diẹ lo si ku ko ko sinu gọta kan ti wọn fẹẹ fo kọja lati gbe e ju sinu ọkọ.

Ṣugbọn ago awọn ọlọpaa lo pada de adiyẹ Portable gbẹyin, wọn gbe e sinu mọto wọn, nibi ti iyawo rẹ naa wa, ti wọn si wa a lọ.

Ninu iwe adehun ti wọn jọ tọwọ bọ lasiko ti Portable fẹẹ ra mọto naa lo ti kọ ọ sibẹ bayii pe,”Emi Badmus Okikiọla Habeeb ti wọn n pe ni Portable, ti mo n gbe ni Odogwu bar, Oke Osa, Sango Ilogbo, nijọba ibilẹ Ado-odo/Ọta, nipinlẹ Ogun, n tọwọ bọwe adehun yii, pe mo ra ọkọ bọginni Mercedes Benz GLE 35, alawọ dudu, pẹlu nọmba iforukọsilẹ 4JDA5HB6GA656575, ni ẹgbẹrun lọna mẹtadinlọgbọn miliọnu Naira (27 million), leyii ti mo ṣeleri lati kọkọ san owo asansilẹ miliọnu mejila Naira ni ọla, ọjọ kẹwaa, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii.

“Ma a san miliọnu marun-un Naira ni igba keji, lọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii. Ma a tun san miliọnu marun-un nigba kẹta, lọjọ kẹwaa, oṣu Keji, ọdun yii. Miliọnu marun-un yooku gbọdọ jẹ sisan lọjọ kẹrinlelogun, oṣu Keji, ọdun yii. Apapọ gbogbo eyi ti o jẹ miliọnu lọna mẹtadinlọgbọn Naira, ti emi Badmus Okikiọla Habeeb, to n jẹ Portable fara mọ pe ọkọ naa duroo re fun mi.

“Ti n ba kuna lati fara mọ gbogbo ajọsọ wa yii, tabi ti n ba kuna lati sanwo gẹgẹ bi a ṣe ti la a kalẹ yii, Ọgbẹni Ogunsanwo Temitọpẹ, ti ileeṣẹ Temmy Autos, to wa ni 15, Adesanya Street, Ẹpẹtẹdo, Ẹpẹ, nipinlẹ Eko, ni aṣẹ lati gba ọkọ Mercedes Benz GLE pada lọwọ emi Badmus Okikiọla Habeeb, ti mo tun n jẹ Portable, lai da owo kankan pada fun mi.

Mo fara mọ ọn, bẹẹ ni mo gba gbogbo ohun to wa ninu iwe adehun ti mo kọ yii, lonii ọjọ kẹsan-an, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024”.

Ṣugbọn Portable ko san owo rẹ to ku, niṣe lo si n sa fun ọmọbinrin to gbe mọto fun un, to si n dunkooko mọ iyẹn.

Ibinu eyi lo mu ki dila naa gba kootu lọ, to si fẹjọ sun nibẹ pe ki wọn ba oun gba owo oun lọwọ Portable. N ni kootu ba fun awọn ọlọpaa niwee aṣẹ pe ki wọn lọọ gbe Portable wa.

Titi ta a fi pari akojọpọ iroyin yii, agọ ọlọpaa ni ọmọ Ọlalọmi wa. Ko ti i sẹni to le sọ boya wọn yoo gbe e lọ sile-ẹjọ tabi wọn maa yanju ọrọ naa labẹ ile.

Leave a Reply