Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Nitori igbesẹ lati lẹ jẹ ki alaafia jọba pada niluu Itapa-Ekiti, to wa nijọba ibilẹ Ọyẹ, nipinlẹ Ekiti, ijọba ti yi ipinnu awọn eeyan ilu naa lori bi wọn ṣe yọ Oloye Kẹhinde Ọsanyingbemi gẹgẹ bii olori Awo ilu naa. Wọn ti da a pada sipo bayii.
Bakan naa nijọba tun rọ Ọwatapa to jẹ ọba alaye ilu naa, Ọba Davido Ajaja, to yọ Olori Awo naa nipo pe ko gba a wọle pada sinu igbimọ aṣejọba rẹ niluu naa ki alaafia le tẹsiwaju niluu naa.
Igbakeji gomina ipinlẹ naa, Arabinrin Monisade Afuyẹ, lo paṣẹ naa lakooko to n pari ẹjọ ati aawọ ati awuyewuye ọrọ oye jijẹ to ti n ṣẹlẹ latigba diẹ laarin Ọba David Ajaja ati Oloye Ẹlẹmọ ti ilu naa, Oloye Isaac Ojo-Ajaja ati Oloye Kẹhinde Babalọla to jẹ Olori Awo ilu.
Tẹ o ba gbagbe, Ọba Ajaja lo ti kọkọ fẹsun kan awọn oloye meji ninu ilu naa pe wọn ko bọwọ fun oun, ati pe wọn n gbe igbesẹ to le mu ẹrẹ ba ipo Ọba Ọwatapa lawujọ, Iwa yii ni ọba alaye yii juwe gẹgẹ bii eyi ti ko yẹ ki wọn ba lọwọ ẹni to wa niru ipo to wa ninu ilu naa.
Nigba to n sọrọ lori rogbodiyan to ti n fi ilu naa lakalaka lati igba diẹ sẹyin, Igbakeji gomina ipinlẹ Ekiti ni oun yi aṣẹ idaduro oloye yii ti ọba alaye yii ti kọkọ pa pada, o ni ki wọn gba a pada sipo rẹ ninu ilu, to si tun pasẹ pe ki Olori Awo yii tọrọ aforiji ni gbangba lọwọ Ọba alaye naa.
Afuyẹ waa paṣẹ fun Ọba Ajaja, pe ko fun Olori Awo naa niyọnda lati le maa ṣe ojuṣe rẹ, ko si le maa ṣe gbogbo gbogbo ètùtù to yẹ gẹgẹ bii ojuṣe rẹ niluu naa.
Nigba to n fesi sọrọ naa, Ọba Ajaja ṣalaye pe oun ti kọkọ kọ iwe ẹsun sijọba ipinlẹ Ekiti, lati le pana aawọ naa. Kabiyesi waa
ṣeleri lati tẹle gbogbo aṣẹ ti ijọba pa fun oun, ati lati ṣe ohun gbogbo lati ri i pe alaafia pada jọba niluu naa.
Awọn oloye mejeeji ti wọn ṣẹṣẹ da pada yii dupẹ lọwọ ijọba ipinlẹ Ekiti, fun bi wọn ṣe da sọrọ naa, ti wọn ko si segbe lẹyin ẹnikankan.