Ṣẹyin naa ti gbọ! Eyi lohun ti dokita sọ nipa ayẹwo ti wọn ṣe lori iku to pa Mohbad

Jọkẹ Amọri

Igbẹjọ to ti n lọ lati ọjọ yii nipa ohun to ṣokunfa iku onkọrin nni, IleriOluwa Alọba, ti gbogbo eeyan tun mọ Mohbad, waye nile-ẹjọ giga kan to wa niluu Ikorodu, nipinlẹ Eko.

Ọpọ awọn ololufẹ ọmọkunrin yii ni wọn kora jọ sibẹ lati gbọ abajade ayẹwo ti wọn lọọ ṣe si oku rẹ ni Oke-Okun, eyi ti wọn ti mu pada wa si orileede wa, ti dokita to ni ayẹwo naa lọwọ si gbe e wa siwaju awọn adajọ atawọn agbẹjọro gbogbo.

Ṣugbọn ko jọ pe awọn eeyan ba ohun ti wọn n reti lori igbẹjọ naa pade. Ohun ti ọpọ tori ẹ lọ si kootu l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu yii, ni pe lọjọ naa ni ayẹwo yoo fidi iri iku to pa ọmọkunrin olorin yii mulẹ.

Ṣugbọn nigba ti dokita n ṣalaye niwaju adajọ, o ni ayẹwo tawọn lọọ ṣe si oku rẹ yii ko ṣafihan iru iku to pa Mohbad gan-an.

Ohun to lo fa eleyii ni pe oku naa ti n jẹra ko too di pe awọn lọọ hu u fun ayẹwo. Dokita yii ni to ba jẹ pe ni bii wakati mẹrinlelogun si mejidinlaaadọta to ti ku lawọn lọọ hu oku naa jade ni, o lo ṣee ṣe ki awọn le ri aridaju awọn nnkan wọnyi. Ṣugbọn nitori pe ẹran ara oku naa ti n jẹra ki wọn too lọọ hu u, eyi ko jẹ ki wọn ri arigbamu kankan di mu lori iku Ilerioluwa.

Yatọ si eyi, Dokita yii ni awọn nnkan toun ṣakiyesi to jẹ iyalẹnu fun oun, ti oun ko si ti i ri iru rẹ ri latigba ti oun ti n ṣiṣẹ yii ni okuta nla kan tawọn ba lori osi oloogbe nigba ti wọn hu u jade ati eyi ti awọn ba ni ẹgbẹ rẹ, o ni oun ko mọ bi okuta naa ṣe debẹ ati bo ṣẹ jẹ.

ALAROYE yoo mu ẹkunrẹrẹ iroyin lori igbẹjọ yii wa fun yin laipẹ

Leave a Reply