Ọrẹ Mohbad tu aṣiri nla ni kootu: Ọrọ ọmọ Wumi ati dukia wa ninu ohun ti Ilerioluwa fi ba iyawo rẹ ja ko too ku

Faith Adebọla

Ọrẹ ati kekere kan to sun mọ Oloogbe Ilerioluwa Ọladimeji Alọba, tawọn eeyan mọ si Mohbad pẹkipẹki, toun naa si jẹ olorin hipọọpu bii tiẹ, Ọgbẹni Ibrahim Oluwatosin Owodunni, tawọn eeyan mọ si Primeboy, ti ṣalaye lẹkun-un-rẹrẹ nipa aawọ ati ija gbigbona to wa laarin Mohbad ati iyawo rẹ, Ọmọwunmi Cynthia Alọba, eyi to fa gbọnmi-si-i omi-o-to lalẹ ọjọ to ṣaaju iku rẹ.

Primeboy ṣiṣọ loju eegun ọrọ yii l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Karun-un, ọdun yii, nigba to wọnu akolo igbẹjọ ni kootu akanṣe kan, nibi ti wọn ti n tọpinpin ohun to ṣokunfa iku Oloogbe Mohbad, iyẹn Coroner Court, eyi to wa waye ninu yara igbẹjọ kẹta, Candide Johnson Court, Ita Ẹlẹwa, niluu Ikorodu, nibi tawọn agbẹjọro ti fi ibeere po o nifun pọ lori iṣẹlẹ ọhun.

Lasiko ti Abilekọ A. Kọlawọle, to jẹ agbẹjọro to ṣoju fun African Women Lawyers Association, n beere ọkan-o-jọkan ibeere lati tuṣu desalẹ ikoko lọwọ Primeboy, ọmọkunrin to wọ awọtẹlẹ funfun, iyẹn singilẹẹti kan, to si wọn aṣọ otutu alawọ burawun sori rẹ, ṣalaye pe:

Ọrẹ ati-kekere lemi ati Mohbad, mi o le ranti igba ta a ti n ṣọrẹ bọ, tori o ti pẹ gan-an. Ni gbogbo asiko ti Mohbad fi wa laye, mo mọ ọn gẹgẹ bii ẹni tori ẹ pe, to ni laakaye, ti ilera rẹ si dara. Iyalẹnu lo jẹ fun mi bawọn kan ṣe n purọ pe Mohbad ni aisan titete gbagbe nnkan, ko sohun to jọ bẹẹ rara.

Lalẹ ọjọ Satide, iyẹn ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023 to lọ sode ariya niluu Ikorodu, nibi to ti lọọ kọrin, emi ati ẹ, atawọn ọrẹ Mohbad kan, la jọ kuro nile ẹ lagbegbe Lẹkki, tori emi fẹ ko kopa nibi ayẹyẹ ọjọọbi ẹgbọn mi kan to fẹẹ waye laarin ọsẹ to n bọ si asiko yẹn. Awa ta a jọ kuro ni Lẹkki ni emi, Mohbad, Spending, ọrẹ Mohbad kan to n jẹ Darocha, Aburo Mohbad, nigba to si ya ni iyawo ẹ waa ba wa pe oun naa fẹẹ tẹle wa. Tori eyi, Mohbad ni a ti pọ ju fun ọkọ jiipu Prado toun, a si haaya ọkọ kan si i.

A dọhun-un, a ṣere, amọ nigba ti oun ati Wunmi ti n bọ ni wọn ti n tahun sira wọn ninu mọto. Ohun ti mo gbọ laarin wọn ni bi Wumi ṣe n fẹsun kan ọkọ rẹ pe o n fọbẹ ẹyin jẹ oun niṣu, o lo ni ọrẹ ikọkọ mi-in lẹyin oun.

Mohbad naa si n fun un lesi tibinu-tibinu pe ‘ṣebi ẹẹkan ṣoṣo pere loun ati-ẹ laṣepọ to fi sọ foun pe oun ti loyun.’ Bakan naa lo tun sọrọ nipa awọn dukia rẹ kan, bii ilẹ ati owo to lo wa nikaawọ awọn mọlẹbi Wumi. Gbogbo bi Wumi ṣe n sọrọ alufaaṣa si i, bẹẹ loun naa n fun un lesi lakọlakọ, Wọn fa ọrọ yii titi de ibi ta a ti lọọ ṣere ni, wọn si tun ko si i nigba ta a n dari lọ sile.

Amọ emi ṣaa tẹnu mọ ọn fun Mohbad pe eyi to sọ yẹn naa ti to, ko dakẹ, mo si ni kawọn mejeeji tiẹ dele na, ki wọn yee ṣe fa-n-fa, amọ wọn ko gbọ, wọn ṣaa n ja niṣo ni.

Ikilọ ti mo ṣe fun Mohbad nipa ija ọhun lo mu ko binu si mi, o ni ko tẹ oun lọrun bi mo ṣe da si i, o ni ṣe emi o gbọ ohun ti iyawo oun n sọ ni, lo ba binu pe ki n bọọlẹ. Nigba ti mi o da a lohun, o waa ba mi, o si bẹrẹ si i gba mi lẹṣẹẹ pe ki n ṣaa bọọlẹ, amọ mi o bọọlẹ.

Bi Primeboy ṣe n tu pẹrẹpẹrẹ ọrọ yii ni gbogbo kootu mi amikanlẹ, nigba mi-in, ọrọ rẹ si paayan lẹrin-in, nigba to ba fesi lọna agalamaṣa gẹgẹ b’awọn ọmọ igboro ṣe maa n ṣọrọ.

Primeboy tun fidi ẹ mulẹ pe ko si apa tabi ipa ọgbẹ kankan lara ọrẹ oun tawọn fi de Lẹkki. O ni irọ gbuu ni bawọn kan ṣe n sọ pe gilaasi ọkọ Prado ge e lọwọ lasiko to n ba oun ja. O ni loootọ lo gba oun lẹṣẹẹ leralera pe koun bọ silẹ, amọ ko ṣẹṣẹ maa ṣe bẹẹ soun nigbakuugba ti nnkan kan ko ba tẹ ẹ lọrun.

Wọn tun beere ohun to mọ nipa iku oloogbe yii, Primeboy si fesi pe bo tilẹ jẹ pe oun ko si lọdọ Mohbad lasiko to fi mi eemi ikẹyin, toun ko si mọ pato ohun to ṣẹlẹ, sibẹ oun mọ pe ejo iku rẹ lọwọ ninu, o ni iku naa ki i ṣe oju lasan.

Nigba ti wọn bi i pe ki lo mu ko sọ bẹẹ, o ni ‘ẹni ti nnkan kan ko ṣe, tara ẹ da ṣaṣa, ta a jọ ṣere loju agbo, ta a si jọ pada sile, to waa dọjọ keji sikẹta, ti wọn lo ku lojiji lai ṣaarẹ, ohun ti mo fi sọ bẹẹ niyẹn.

Ọpọ ibeere mi-in tawọn lọọya oluwadii n beere lọwọ ẹlẹrii yii lo ni oun ko le sọ, bẹẹ ladajọ ati awọn agbẹjọro mi-in n ta ko ibeere ẹlẹgbẹ wọn, ti wọn si n wọgi le e, wọn ni ibeere naa ko ba lajori ohun ti kootu ọhun n wadii rẹ mu. Lara ibeere ọhun ni nigba ti lọọya to n ṣoju fun iyawo Mohbad beere lọwọ Primeboy pe awọn ija wo lo waye laarin oun ati Oloogbe ni gbọngan ariya Obi Cubana, niṣe ni wọn ta ko ibeere yii, wọn lo ti kọja iwadii ti wọn n ṣe lọwọ.

Laarin kan, adajọ sọrọ si lọọya to duro fun Primeboy, o ni imura onibaara rẹ ko boju mu to nile-ẹjọ pẹlu singilẹẹti ati aṣọ pijamas ti ko de bọtinni rẹ to wọ, loju-ẹsẹ si ni agbẹjọro ọhun ti Primeboy ti tọrọ aforiji leralera lọwọ adajọ naa.

Fun bii wakati meji gbako ni Primeboy fi n ṣalaye ẹnu rẹ, o rojọ, ẹnu rẹ fẹrẹ bo lori iduro to wa. Nigba ti agbẹjọro rẹ si pe akiyesi adajọ si iduro rẹ, pe ki wọn fun un lanfaani lati jokoo sori aga, adajọ ni rara, o ni ọdọkunrin ṣi ni, iduro naa ko ti i pọ ju fun un.

Ṣa, Primeboy ni ọrọ ọmọ ọwọ Wunmi, atawọn ẹsun fifọbẹ ẹyin jẹ ara wọn niṣu, ati ọrọ dukia lo fa ija nla laarin tọkọ-taya naa.

Gbogbo iwadii ati igbẹjọ yii ko ṣẹyin Baba Mohbad, Alagba Joseph Alọba, toun naa wa nikalẹ ni kootu, atawọn mọlẹbi rẹ kan. Amọ Iyawo Mohbad, ati Iya Mohbad ko wa.

Leave a Reply