Adewale Adeoye
Pẹlu bawọn ẹgbẹ oṣiṣẹ orileede Naijiria ‘Nigeria Labour Congress’ (NLC) ati ẹgbẹ awọn ọlọja, ‘Trade Union Congress’ (TUC) ṣe faake kọri lori ọrọ owo-oṣu tuntun ti wọn lawọn fẹẹ gba lọwọ ijọba orileede yii, ti wọn si ti fun wọn ni gbedeke ipari oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, afaimọ ki wahala nla mi-in ma ṣẹlẹ laarin awọn aṣoju ẹgbẹ mejeeji naa ati ijọba apapọ. Ẹgbẹrun mẹrinlelaaadọta (N54,000) Naira lowo oṣu tuntun tijọba lawọn fẹẹ san, ṣugbọn awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ orileede yii ta ku pe ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta o le ẹgbẹrun mẹẹẹdogun Naira ((N615,000) lawọn maa gba, nitori bi ọrọ aje ṣe ri lorileede yii to jẹ pe ojoojumọ lọja n gbowo lori.
Alukoro ẹgbẹ oṣiṣẹ orileede yii, Ọgbẹni Benson Upah, to ba awọn oniroyin sọrọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu yii, lẹyin ipade pataki kan to waye laarin awọn aṣoju ẹgbẹ mejeeji ati awọn tijọba, sọ pe ẹgbẹrun mẹrinlelaaadọta Naira lowo oṣu tuntun tijọba lawọn fẹẹ san, ṣugbọn tawọn faake kọri pe ko sohun to jọ bẹẹ rara, ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta o le ẹgbẹrun mẹẹẹdogun Naira (625, 000) lowo tawọn n beere fun lọwọ ijọba gẹgẹ bii owo oṣu tuntun.
Ni nnkan bii ọsẹ bii meloo sẹyin bayii nijọba orileede Naijiria fi ẹgbẹrun mejidinlaaadọta (N48,000) lọ ẹgbẹ oṣiṣẹ orileede yii gẹgẹ bii owo oṣu tuntun tijọba yoo maa san, ṣugbọn loju-ẹsẹ ni wọn ti faake kọri pe awọn ko ni i gbowo naa lọwọ ijọba apapọ, nitori ko to lati gbọ bukaata, nitori ti nnkan n fojoojumọ gbowo lori si i.
Ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta o le ẹgbẹrun mẹẹẹdogun Naira (625,000) lowo oṣu tuntun ti ẹgbẹ oṣiṣẹ orileede yii lawọn maa gba lọwọ ijọba, koda, wọn ni o ṣee ṣe ki owo naa tun lọ soke si i bi ijọba orileede yii ko ba wa nnkan ṣe si bi ọja atawọn nnkan ṣe n fojoojumọ gbowo lori si i.
Ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu ta a wa ninu rẹ yii, ni ọjọ tawọn ẹgbẹ oṣiṣẹ fun awọn ijọba orileede Naijiria da lati kede owo-oṣu tuntun tijọba fẹẹ san fun wọn.