Ijamba mọto mu ẹmi ọlọkada ati ero meji lọ ni Bọlọrunduro

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Eeyan meji ni wọn ba iku ojiji pade, ti ẹni kẹta wọn si wa lẹsẹ-kan-aye, ẹsẹ-kan-ọrun, lẹyin ti ọkọ akọwọọrin kan kọ lu wọn lori ọkada ti wọn wa lagbegbe Bọlọrunduro, nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ondo, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii.

Iṣẹlẹ ọhun ni wọn lo waye laarin ọkada kan ti nọmba rẹ jẹ NND 218 PC, ati ọkọ Toyota Hilux ti ko ni nọmba rara labule kan ti wọn n pe ni Ẹlẹmọṣọ, eyi to wa loju ọna marosẹ Ondo si Akurẹ.

Ẹnikan to wa nitosi lasiko ti iṣẹlẹ ọhun waye ṣalaye fun ALAROYE pe ere asapajude ti ọlọkada ati ọkọ Toyota naa jọ n sa lo ṣokunfa ijamba ọhun, eyi to fẹmi awọn meji ṣofo lairo tẹlẹ.

O ni oun ṣakiyesi pe ṣọọṣi kan ni awọn mẹtẹẹta, iyẹn ọlọkada naa pẹlu awọn ero meji to wa lẹyin rẹ ti n bọ lati ọna Bọlọrunduro, ti awakọ Toyota ati ẹni to n tẹle e si n bọ lati ọna ilu Ondo, o da bii ẹni pe Abuja ni wọn n lọ ni ti wọn.

O ni asiko ti ọlọkada yii fẹẹ sare ya ọkọ to wa niwaju rẹ silẹ lai wo ọna daadaa ko too ṣe bẹẹ lo lọọ pade ọkọ Toyota toun naa n ba ere buruku bọ loju ọna tirẹ. O ni ko si bi awakọ naa ti fẹẹ ṣe e ti ko ni i kọ lu ọlọkada ọhun, nitori ọrọ naa ti bọ si pajawiri, bẹẹ ni ko si bo ṣe le pẹwọ fun un mọ.

Loju-ẹsẹ lo ni ọkọ naa ti tẹ awọn meji pa, ti ẹni kẹta si wa lẹsẹ-kan-aye ẹsẹ-kan-ọrun titi di asiko to n ba awa sọrọ nipa iṣẹlẹ naa.

Ọkọ Toyota naa, ninu eyi ti awakọ kan pẹlu ọlọpaa kan wa ninu rẹ lo ni wọn ko duro rara lẹyin iṣẹlẹ naa nitori ibẹru, o ni bi ọkọ naa ti kọ lu wọn tan lo ti gbe ere buruku da si i, to si sa lọ.

ALAROYE gbọ pe awọn ero to n kọja lasiko naa ni wọn pada ko oku awọn to ba iṣẹlẹ ọhun rin lọ si mọṣuari, ti wọn si tun gbe ẹni to fara pa lọ si ọsibitu fun itọju.

Leave a Reply