Haa! Ẹ wo aduru owo ati dukia Emefiele tijọba fẹẹ gbẹsẹ le

Monisọla Saka

Ile-ẹjọ giga kan to fikalẹ siluu Eko, to n gbọ ẹsun ti ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra lorilẹ-ede wa, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), pe ta ko olori banki ilẹ wa tẹlẹ, Godwin Emefiele, lori ikowojẹ ati gbigba ọna ẹburu sọ owo ilu di tiẹ lasiko to wa nipo ti paṣẹ pe ki ijọba gbẹsẹ le awọn owo kan to le ni miliọnu dọla mẹrin ($4,719,054) ati owo mi-in to le ni miliọnu mẹjọ Naira (830,875,611), to fi mọ awọn dukia mi-in to jẹ ti olujẹjọ.

L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni Onidaajọ Yellim Bogoro, paṣẹ naa, lẹyin ti amofin Bilkisu Buhari ati C. C. Chineye, ti wọn jẹ agbẹjọro fun EFCC gbe ọrọ naa siwaju rẹ.

Lẹyin ti adajọ gbọ, to si gba atotonu ẹnu awọn lọọya EFCC mejeeji yii wọle, lo sọ awọn nnkan to yẹ ni ṣiṣe ki wọn too bẹrẹ igbesẹ lori awọn owo ati dukia ti wọn ni olujẹjọ fi ọna eru ko jọ ni gbigbẹsẹ le.

Lara awọn owo Emefiele tijọba yoo gbẹsẹ-le, ni wọn ni o tọju pamọ si First Bank, Titan Bank ati Zenith Bank, eyi ti Omoile Anita Joy, Deep Blue Energy Service Limited, Exactquote Bureau De Change Limited, Lipam Investment Services Limited, Tatler Services Limited, Rosajul Global Resources Limited ati TIL Communication Nigeria Limited, n ṣakoso rẹ.

Bakan naa ni ijọba n gbero lati gba awọn ile ati ilẹ to ni sawọn agbegbe bii 2, Ọtunba Elegushi 2nd Avenue, (ti wọn n pe ni Club Road tẹlẹ), Ikoyi, nipinlẹ Eko, nibi ti ile alaja mọkanla to ni ojule mẹrinlelaaadọrun-un, ti wọn n kọ lọwọ wa. AM Plaza, toun naa tun jẹ ile alaja mọkanla ti wọn fi kọ kikida ọfiisi, lagbegbe 1E, Ọtunba Adedoyin Crescent, Lekki Peninsula Scheme 1, nipinlẹ Eko. Omi-in tun ni Imore Industrial Park 1, Esa Street. Imoore Land yii lo ra lọdọ Deep Bive Industrial Town, ijọba ibilẹ Onitẹsiwaju Oriade, to wa ninu ijọba ibilẹ Amuwo Ọdọfin, nipinlẹ Eko.

Emefiele tun ni ile ikẹrusi nla Mitrewood and Tatler Warehouse, to jẹ ileeṣẹ ti wọn n ko awọn aga, tebu ati bẹẹdi igbalode pamọ si ni Bogijẹ, nitosi abule Owolomi, nijọba ibilẹ Ibẹju-Lekki, Ẹlẹmọrọ, nipinlẹ Eko.

Bakan naa lo tun ra dukia meji kan lati ileeṣẹ Chevron Nigeria, lagbegbe Lakes Estate, Lekki, nipinlẹ Eko.

Awọn dukia rẹ mi-in ni ilẹ pulọọti kan to wa ni Lẹkki Foreshore Estate Scheme, Block A, Plot 4, Foreshore Estate, ijọba ibilẹ Eti-Ọsa, nipinlẹ Eko. Ati Estate nla kan to wa ni 100, Cottonwood Coppel Texas Drive, Coppel, Texas, lorilẹ-ede Amẹrika. Ilẹ kan to wa ni 1, Bunmi Owulude Street, Maruwa, Lekki Phase, l’Ekoo, ati ile kan to wa ni 8, Bayọ Kuku Road, Ikoyi, nipinlẹ Eko.

Lara nnkan ti ajọ EFCC fẹ, ti wọn si gbe siwaju ile-ẹjọ ni pe ki ijọba apapọ kọkọ gbẹsẹ-le gbogbo awọn owo to wa ninu banki oriṣiiriṣii ti wọn mẹnuba loke yii, ati gbogbo awọn dukia ti wọn darukọ, nitori ọna eru, ti ko bofin mu ni o gba ko wọn jọ.

“Ki ile-ẹjọ paṣẹ pe ki ẹnikẹni to ba nifẹẹ ninu ọrọ owo ati dukia Emefiele yii lọọ kede ninu iwe iroyin to n kale kako yoowu, pẹlu alaye lori idi ti wọn ko gbọdọ fi gbẹsẹ le e. Ki iru ẹni bẹẹ si wa si ile-ẹjọ yii laarin ọjọ mẹrinla lati waa sọ idi ti ko fi yẹ ki wọn gbe iru igbesẹ lati dari gbogbo dukia ọhun si apo ijọba apapọ”.

Labẹ abala kẹtadinlogun, iwe ofin orilẹ-ede Naijiria ti ọdun 2006, to tako iwa jibiti, ni ajọ EFCC lo nile-ẹjọ.

Ọjọ keji, oṣu Keje, ọdun yii, ni adajọ sun igbẹjọ tuntun, nibi ti wọn yoo ti pari ẹjọ lori bi awọn dukia ọhun yoo ṣe jẹ ti ijọba apapọ yoo ti waye.

Leave a Reply