Ogun eeka ilẹ igbo ni Jimoh gbin si Ẹda-Ile, l’Ekiti, ọwọ ti tẹ ẹ 

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ọwọ ọlọpaa ṣọgbo-ṣogbo, ti ijọba ipinlẹ Ekiti (Ekiti State Agro Marshall) ti tẹ ọkunrin eni ọdun mejidinlaaadọrin kan, Ọgbẹni David Jimoh, lori ẹsun gbingbin ati siṣe owo egboogi oloro igbo.

Gẹgẹ bi ọga agba awọn ọlọpa ṣọgbo-ṣọgbo nipinlẹ Ekiti yii, Ọgbẹni Ọlamide Oni, ṣe sọ lakooko ti wọn ṣe afihan ọdaran naa, o ni yatọ si pe ọdaran yii n ta igbo fun awọn oniṣowo igbo, o tun to eeka ogun oko igbo to da si ilu Eda-Ile, nijọba ibilẹ Àríwá, ìjọba (Ekiti  East) nipinlẹ Ekiti

O sọ pe ọwọ wọn tẹ ọdaran naa lẹyin ti awọn araalu kan ta wọn lolobo pe o ti wa lagbegbe naa lati bii ogun ọdun, to si ti n ṣe owo gbingbin egboogi oloro naa. O fi kun pe niṣe ni Jimọh kọju ija si awọn ẹṣọ ọlọpaa aṣọgbo naa pẹlu bo ṣe n yinbọn soke ninu igbo naa, eleyi to ba wọn l’ẹru pupọ.

O ṣalaye pe ọkunrin naa, ti ko ni iṣẹ miran ju iṣẹ gbingbin igbo jẹ ọmọ bibi ilu Ogbẹsẹ, nijọba ipinlẹ Ondo, lọwọ tẹ lakooko tawọn ṣe abẹwo pajawiri si agbegbe naa.

Oni sọ pe ọkunrin naa ti wa ninu owo igbo gbingbin naa lati bii ọgbọn ọdun sẹyin ki ọwọ wọn too tẹ ẹ. Nigba ti wọn fẹẹ mu un lo gbiyanju lati fun ọlọpaa aṣọgbo naa lowo, ṣugbọn wọn ko lati gba a a.

O ṣalaye pe wọn yoo jọwọ ọdaran naa fun awọn ọlọpaa lati le foju wina ofin ni kete ti wọn ba ti pari iwadii lori ọrọ naa.

Lakoko ti awọn akọroyin n fi ọrọ wa ọdaran naa lẹnu wo, o sọ pe loootọ loun ṣẹ ẹṣẹ naa, ati pe o ti to ọjọ mẹta ti oun ti n ṣiṣẹ gbingbin ati tita egboogi oloro.

 

Leave a Reply