Ọlawale Ajao, Ibadan
Nitori bi gbogbo nnkan ṣe gbowo lori, ti owo-oṣu ti awọn oṣiṣẹ n gba ko si to wọn i na mọ, ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ nilẹ yii, ti wọn jẹ ẹka olokoowo, iyẹn Trade Union Congress (TUC) ti yari, wọn lawọn ko fara mọ owo ti ijọba n yọ ninu owo-oṣu awọn mọ.
Nibi apero ti ẹgbẹ TUC, ẹka ilẹ Yoruba, ta a mọ si ẹkun Iwọ-Oorun Ariwa orileede yii, ṣe ni gbọngan International Conference Centre, ninu ọgba Fasiti Ibadan, ni wọn ti sọrọ naa lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii.
Owo ti ijọba n yọ ninu owo-oṣu wọn yii lo da bii ajọ ti wọn n ba awọn oṣiṣẹ da pamọ, eyi ti wọn yoo pada gba lẹyin igba ti wọn ba fẹyin ti lẹnu iṣẹ.
Ṣugbọn ninu apero ọlọjọ meji wọn ọhun, eyi to waye l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtalelogun (23), ati Furaidee, ọjọ kẹrinlelogun (24), oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, ni gbogbo awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ yii ti fohun ṣọkan pe awọn ko fara mọ owo ti wọn n yọ ninu owo-oṣu awọn yii mọ, nitori gbogbo owo ọhun gan-an funra rẹ ko too na pẹlu bi ohun gbogbo ti ṣe n gbowo lori lojoojumọ lorileede yii, ti ayipada ko si ba owo-oṣu tawọn oṣiṣẹ n gba, eyi ti ko to nnkan tẹlẹ.
Eyi lo mu ki Aarẹ ẹgbẹ TUC nilẹ yii, Ọgbẹni Festus Osifo, rọ ijọba apapọ, labẹ akoso Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, lati ṣatunṣe gidi si eto ọrọ-aje orileede yii, ki owo-oṣu ti awọn oṣiṣẹ n gba le to wọn ọn gbọ bukaata, dipo bi nnkan se ri lasiko yii, to jẹ pe oṣiṣẹ ijọba kan ko lagbara lati ra ẹyọ apo irẹsi kan sile mọ bayii nitori owo-oṣu wọn ko to nnkan.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “A n pe ara wa ni aṣiwaju fawọn orileede yooku l’Afrika, sibẹsibẹ, iya n jẹ awọn oṣiṣẹ, wọn n rare, nitori ijọba o sanwo oṣu to nitumọ fun wọn.
“Pẹlu bi eto ọrọ aje orileede yii ko ṣe duro soju kan naa, ọdun meji meji lo yẹ ki ijọba apapọ maa ṣagbeyẹwo iye to yẹ ki awọn oṣiṣẹ maa gba gẹgẹ bii owo-oṣu”.
Ṣaaju ni Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ẹni ti Igbakeji rẹ, Amofin Bayọ Lawal, ṣoju fun, ti fi awọn oṣiṣẹ ipinlẹ naa lọkan balẹ pe ijọba oun ko ni i fọrọ ìgbáyé-gbádùn awọn oṣiṣẹ ṣere.
Nigba to n dupẹ lọwọ Gomina Makinde fun bo ṣe ka ọrọ ìgbáyé-gbádùn awọn oṣiṣẹ ipinlẹ naa si, Alaga ẹgbẹ TUC nipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Bọsun Ọlabiyi-Agoro, ṣeleri pe loorekoore lẹka ẹgbẹ ọhun nilẹ Yoruba yoo maa ṣe iru apero yii lati le maa jiroro lori ọna ti igbe aye irọrun yoo fi maa ba gbogbo ọmọ ẹgbẹ ọhun.