Tinubu ni kẹ ẹ gba mu ti ogun ba fi le bẹ silẹ ni Kano – Atiku

Monisọla Saka

Igbakeji Aarẹ ilẹ wa nigba kan ri, Alaaji Atiku Abubakar, ti ke si gbogbo awọn eeyan pe ti wahala kankan ba fi le bẹ silẹ nipinlẹ Kano lori ọrọ iyansipo ọba, Aarẹ Tinubu ni ki wọn mu fun un.

Ẹmia ti wọn ṣẹṣẹ rọ loye niluu naa, Aminu Ado Bayero, ni Atiku to bu ẹnu atẹ lu Tinubu sọ pe o n ṣegbe fun, agaga pẹlu bo ṣe ni kawọn ọmọ ogun sin in lọ si aafin tiẹ laaarọ kutu ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii.

Atiku sọrọ yii lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, pe ọrọ wọn nipinlẹ Kano ni, niwọn igba ti Gomina Abba Yusuf funra ẹ ti tun ofin to ni i ṣe pẹlu ọba jijẹ nipinlẹ Kano ṣe, eyi to ṣokunfa bi Sanusi Lamido Sanusi, ti wọn rọ loye lọdun mẹrin sẹyin fi pada sipo.

O ni igbesẹ ijọba apapọ, to fẹẹ maa yọjuran si ọrọ wọn nipinlẹ Kano yii ta ko iwe ofin ilẹ Naijiria, ọdun 1999.

O ni ki Tinubu ma gbe igbesẹ ti yoo da omi alaafia Kano, ti wọn mọ gẹgẹ bi ilu to toro ru.

“Ohun ti ijọba apapọ n ṣe bi wọn ṣe ko ṣọja lọ si Kano lori ọrọ oye ọba jẹ ohun to le ba alaafia ilu naa jẹ, ti yoo si bi rogbodiyan nipinlẹ naa, eyi si tun ta ko ofin orilẹ-ede yii.

“Lojuna ati le ṣe ojuṣe wọn ninu ofin ṣiṣe, ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kano ti ṣatunṣe si ofin to rọ mọ ọba jijẹ lọdun yii ni ibamu pẹlu abala kẹrin iwe ofin ọdun 1999, gomina ipinlẹ naa, Abba Kabir Yusuf, si ti buwọ lu iwe ofin naa. Ofin yii ti waa fagi le ti ọdun 2019, to fọ ipo ọba niluu Kano si ọna marun-un.

“Gbogbo nnnkan to ṣẹlẹ yii lo waye ni ibamu pẹlu ofin ati agbara to wa nikaawọ gomina, gẹgẹ bi abala karun-un iwe ofin ọdun 1999 ṣe la a kalẹ, ati ni ibamu pẹlu eto awọn afọbajẹ Kano, ni wọn fi tun gbe Sanusi Lamido Sanusi (Muhammadu Sanusi Keji), pada sori ipo gẹgẹ bii Ẹmia kẹrindinlogun ilu Kano, ti wọn si ti fi lẹta iyansipo rẹ le e lọwọ.

“O waa ya ni lẹnu pe nidaaji ọjọ Satide, ni nnkan bii aago marun-un aabọ geerege, Ẹmia ilu Kano ti wọn ṣẹṣẹ gbe kuro, Ọba Aminu Ado Bayero, ti ijọba apapọ n ṣegbe fun, pada si aafin Nasarawa, nipinlẹ Kano, nibi ti Ẹmia Sanusi Lamido Sanusi, ti wọn ṣẹṣẹ da pada sori ipo wa, lagbebe Gidan Dabo, nibi to jẹ ile Ẹmia Kano gangan.

“Nidii eyi, ko ba ma ti rọrun fun Ẹmia atijọ yii lati pada si aafin Nasarawa lai si ọwọ ijọba apapọ nibẹ, pẹlu iranlọwọ awọn ṣọja atawọn ẹṣọ alaabo mi-in ti wọn ko tẹle e lẹyin. Ilo ọmọ ogun ninu iru ọrọ bayii tabuku ileeṣẹ ologun ilẹ Naijiria.

“A ni lati ran ijọba Tinubu leti pe ilu to kun fun iṣọkan ati alaafia ni ipinlẹ Kano, latọdunmọdun. Gbogbo ọna lati da omi alaafia ilu ọhun ru ni a o si lodi si. Ṣe ẹ ranti pe lọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹta, ọdun, 2020, ni wọn rọ Sanusi loye nipo ọba, Kano si n bẹ lalaafia rẹ lai si wahala tabi idarudapọ kankan sibẹ naa”.

O ni awọn n sọ gbangba gbàǹgbà bayii pe ti ofin ba dẹnu kọlẹ latari idi kan tabi omi-in nipinlẹ Kano, paapaa ju lọ igboro ilu yii, ijọba apapọ ni ki wọn mu, nitori bo ṣe n daabo bo Ẹmia Kano tẹlẹ, Aminu Ado Bayero, lati tun pada wa siluu nitori rogbodiyan lo n fa lẹsẹ yẹn.

Leave a Reply