Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ijaya ati jinni-jinni lo bo gbogbo awọn eeyan Omisanjana, niluu Ado-Ekiti, lalẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, pẹlu bi ọlọpaa kan se ṣadeede fa ibọn yọ, to si pa eeyan meji ni deede agogo mẹwaa alẹ niwaju ileepo kan ni adugbo naa.
Ọlọpaa to ṣiṣẹ buruku ọhun ni wọn lo n ṣiṣẹ pẹlu ajọ ọlọpaa ayaraṣaṣa( Rapid Response Squad RSS). Gẹgẹ bi awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣe sọ, wọn ni awakọ kan to wa ọkọ Lexus, lo muti yo to fi lọọ kọ lu ọmọ Yahoo kan ni adugbo naa.
Ni kete tiṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni awọn ọmọ Yahoo ẹgbẹ rẹ yooku rọ jade, ti wọn si fẹẹ dana sun ọkọ naa, eyi lo fa a ti dẹrẹba yii ti ẹru n ba fi pe awọn ọlọpaa ẹka RSS yii, pe ki wọn maa bọ ni adugbo naa.
Ni kete ti awọn ọmọ Yahoo foju gan-an-ni awọn ọlọpaa yii ni inu bi wọn, ti awọn ọdọ adugbo naa si darapọ mọ awọn ọmọ Yahoo wọnyi. Ọrọ yii lo pada ja si awuyewuye laarin awọn ọlọpaa atawọn ọmọ Yahoo wọnyi, lẹyin ti awọn ọdọ adugbo naa ti ko din ni aadọta darapọ mọ wọn.
Awọn ọlọpaa wọnyi ni wọn gbiyanju lati mu awakọ yii jade kuro ni adugbo naa, ati lati lati da awọn ọdọ wọnyi lẹkun ki wọn ma le dana sun ọkọ naa, ṣugbọn niṣe ni wọn kọ, ti wọn ko gba awọn ọlọpaa laaye, wọn ni afi ti awọn ba dana sun ọkọ naa dandan.
Eyi lo fa a ti awọn ọlọpaa yii fi ranṣẹ si awọn ẹlẹgbẹ wọn yooku, ti ọrọ si di bo-o-lọ-o-yago laarin awọn agbofinro yii atawọn ọdọ adugbo naa. Ni kete ti wọn ya wọ adugbo naa ni wọn bẹrẹ si i yinbọn soke, ti ibọn si ba meji lara awọn ọdọ wọnyi, ti wọn si jẹ ipe Ọlọrun loju-ẹsẹ.
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abùtù sọ ninu iwe kan to kọ lorukọ Kọmiṣanna ipinlẹ naa, Ọgbẹni Akinwale Adeniran, lo ti ṣalaye bi iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ. O ni o jẹ oun ìbànújẹ gidigidi fun oun ati awọn ọlọpaa yooku nipinlẹ Ekiti.
Abutu ni wọn ti gba ibọn lọwọ ọlọpaa to sadeede yinbọn pa awọn ọdọ meji naa, to si ti wa ni atimole lọwọlọwọ bayii, ti gbogbo igbesẹ si n lọ lati jẹ ki ọlọpaa naa le foju wina ofin.
O fi kun un pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti kan si mọlẹbi awọn ọdọ mejeeji ti wọn ku naa lati ba wọn kẹdun, ati lati sọ fún wọn pe iwadii okodoro ọrọ yoo waye lori iṣẹlẹ naa, ti ọlọpaa to yinbọn naa yoo si foju ba ile-ẹjọ naa laipẹ.