Iyawo Ọmọọba Harry kọ lẹta si Oluwoo o, eyi lohun to wa nibẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Iyawo Ọmọọba Harry, Meghan Markle, ti kọ iwe idupẹ si Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, fun bo ṣe gba oun lalejo lasiko abẹwo ọlọjọ mẹta to ṣe si orileede Naijiria laipẹ yii.

Meghan sọ pe inu oun dun pupọ fun orukọ ‘Adetokunbọ’ ti Oluwoo fun oun lasiko abẹwo naa.

Tẹ o ba gbagbe, Ọmọọba Harry ati iyawo rẹ, Duke ati Duchess ti Sussex, ni wọn ṣabẹwo si orileede Naijiria loṣu Karun-un ọdun yii.

Lasiko abẹwo yẹn, Oluwoo ti ilu Iwo nikan ni ọba ilẹ Yoruba ti wọn fiwe pe lati wa nibi ayẹsi pataki ti wọn ṣe fun tọkọ-taya yii ni Delborough Hotel, Ikoyi, niluu Eko.

Nibi eto naa ni Ọba Akanbi ti fun Meghan ni orukọ ilẹ Yoruba, o pe e ni Adetokunbọ, bẹẹ lo fun un ni aṣọ-ofi to jọju pẹlu ilẹkẹ iyun.

Ninu lẹta idupẹ ti Meghan fi ranṣẹ si Oluwoo, o ni o jọ oun loju pupọ bi kabiesi ṣe ṣetọju oun ati ọkọ oun lasiko abẹwo naa.

O ni oun mọ riri orukọ ‘Adetokunbọ’ ti Oluwoo fun oun, pẹlu ileri pe oun yoo ṣamulo orukọ naa pẹlu iyi ati ẹyẹ to pọ.

Meghan ni ayẹwo ti awọn ṣe si orileede yii ṣe pataki lati jẹ ki awọn mọ nipa orirun awọn, eleyii ti awọn yoo fi kọ arọmọdọmọ awọn.

O sọ siwaju pe pẹlu abẹwo naa, oun mọ pe pipada bọ wa sile awọn ko ni i pẹ mọ rara.

 

Leave a Reply