Adewale Adeoye
Ọdọ ọlọpaa Zone 2, ni Onikan, nipinlẹ Eko, ni Omidan Ruth Livinus, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn to n gbe lagbegbe Ajah, nipinlẹ Eko, to ji ara rẹ gbe loṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, wa bayii. O n ran awọn ọlọpaa naa lọwọ ninu iwadii wọn nipa ẹsun ti wọn fi kan an ni.
Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ni wọn safihan Ruth ati ololufẹ rẹ, Ọgbẹni Isaac Gabriel, ẹni ọdun mẹrinlelogun kan ti wọn ni wọn jọọ lẹdi apo pọ fi hu iwa palapala naa fawọn oniroyin.
ALAROYE gbọ pe loṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, ni Ruth ati ololufẹ rẹ lẹdi apo pọ, ti wọn si parọ bantabanta fun Iya Ruth to jẹ opo pe awọn ajinigbe kan ti ji oun gbe, miliọnu marun-un Naira lowo ti wọn ni ki Iya Ruth lọọ mu wa ko too di pe wọn maa ju u silẹ lahaamọ wọn. Ẹgbẹrun lọna ọgọta Naira lowo ti wọn kọkọ fi ranṣẹ si awọn ajinigbe naa ko too di pe ọwọ tẹ awọn mejeeji.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ẹka Zone 2, Onikan S.P Ayuba Umma, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrinla, oṣu yii, sọ pe, ajọmọ Ruth ati ololufe rẹ ni pe ki wọn ji ara wọn gbe pamọ lati fi gbowo lọwọ Iya Ruth to jẹ opo. Miliọnu marun-un Naira lowo ti wọn n beere fun lọwọ iya naa, nọmba foonu ajoji kan ni wọn fi peobinrin ọhun, wọn fun un ni akaunti to maa sanwo si, lẹyin naa ni wọn tun fi fọto Ruth ti wọn di lọwọ-lẹsẹ ninu igbo ranṣẹ si iya rẹ lati sọ fun un pe awọn ko fọrọ naa ṣere rara. Ṣugbọn lẹyin ti wọn san ẹgbẹrun lọna ọgọta Naira akọkọ sinu akanti ti Ruth ati ololufe rẹ fi ranṣẹ si wọn lọwọ tẹ wọn.
Ruth loun paapaa kabaamọ iwa laabi toun hu naa. O ni, ‘ Kẹ ẹ si maa wo o, ololufẹ mi lo sọ pe ki n ji ara mi gbe o. Owo ti ma a fi ṣi ṣọọbu ni mo n wa, nigba ti mi o lowo lọwọ, toun naa ko ni lọwọ, lo ba kọ mi pe ki n parọ pe awọn ajinigbe kan ti ji mi gbe, agbegbe Ikorodu, nipinlẹ Eko, la sa lọ. Ibẹ naa la wa ko too di pe awọn ọlọpaa waa mu wa.
Ṣa o, ọtọ lọrọ ti Gabriel to jẹ ọmọ ilu Benue ti i ṣe ololufẹ Ruth bawọn oniroyin sọ. Ohun to sọ ni pe Ruth gan-an lo mu aba naa wa pe k’oun ran oun lọwọ koun le ri owo gidi gba lọwọ iya oun, tawọn mejeeji si jọọ fẹnuko pe kawọn parọ pe awọn ajinigbe ni wọn ji Ruth gbe. ‘’Emi kọ ni mo sọ pe ko ji ara rẹ gbe, mo kan ṣatilẹyin fun un ni. Irọ to kọkọ fẹẹ pa fun ẹgbọn rẹ kan ni pe ara oun ko ya, mo sọ fun un pe owo kekere ni aba naa maa mu wa, lo ba loun maa sọ pe awọn ajinigbe ji oun gbe.
Akọ iṣẹ lawọn ọlọpaa ti wọn fọrọ ọhun to leti ṣe ko too di pe wọn mu awọn afurasi ọdaran meji naa niluu Ikorodu, nipinlẹ Eko, nibi ti wọn ji ara wọn gbe pamọ si.