Ali Ndume ti sọrọ o: Ko sẹni to le le mi ninu ẹgbẹ APC, a jọ da a silẹ ni

Adewale adeoye

Senatọ Ali Ndume, to n ṣoju ẹkun Borno-South, nipinlẹ Borno, ti ni lọwọ yii, ojulowo ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC loun, toun ko si ti i ṣetan lati fi ẹgbẹ naa silẹ, afi ti gomina ipinlẹ oun, Ọjọgbọn Babagana Zulum, naa ba ṣetan lati kuro ninu ẹgbẹ oṣelu yii nikan lo ku.

Ọrọ alufanṣa kan ni wọn sọ pe Sẹnetọ naa sọ si Olori orileede yii, Aarẹ Tinubu, lori afẹfẹ, eyi to mu kawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC nileegbimọ aṣofin agba niluu Abuja,  ditẹ rẹ, ti wọn si gba ipo agbẹnusọ olori ọmọ ẹgbẹ to pọ ju lọ nileegbimọ (Chief Whip), to di mu kuro lọwọ rẹ. Lẹyin naa ni alaga ẹgbẹ yii, Alhaji Umar Ganduje, ati akọwe gbogbogboo ẹgbẹ naa tun sọ fun un pe ko fi ẹgbẹ yii silẹ, ko lọọ darapọ mọ ẹgbẹ alatako yoowu to ba wu u. Ṣugbọn ni bayii,  Ndume ti ni niwọn igba to jẹ pe lara awọn to da ẹgbẹ naa silẹ loun, ko sẹnikan to le dunkooko mọ oun, tabi pe ki wọn fọwọ lalẹ f’oun ninu ẹgbẹ yii.

Ndume sọrọ ọhun di mimọ nile rẹ to wa niluu Maiduguri, nipinlẹ Borno, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keje, ọdun yii, lasiko tawọn ololufẹ rẹ kan ti wọn jẹ obinrin ninu ẹgbẹ naa waa ki i sile. Awọn obinrin ẹgbẹ naa sọ pe awọn ṣetan lati ṣewọde ita gbangba nitori rẹ lọ sileegbimọ aṣofin agba l’Abuja, nitori pe aṣaaju awọn ni lọjọ-kọjọ, ati pe awọn ko nifẹẹ si bawọn kan ṣe ditẹ gba ipo to wa nileegbimọ aṣofin agba lọwọ rẹ.

Lasiko to n ki wọn kaabọ sile rẹ lo ti sọ pe, ‘Emi o ma ni i da wọn lohun o, wọn ni ki n kuro lẹgbẹẹ APC, ki lọọ darapọ mọ ẹgbẹ alatako yoowu to ba wu mi, ohun ti ma a sọ fawọn to sọ bẹẹ ni pe Ọlọrun Ọba nikan lo n gbe agbara fẹni to ba wu u, ki i ṣe ẹda kankan. Mo fẹẹ fi da gbogbo eeyan loju pe mi o ki i ṣe àṣáwọ̀ ninu ẹgbẹ APC rara. Aṣaaju wa ninu ẹgbẹ APC nipinlẹ Borno ni Gomina Zulum jẹ, inu ẹgbẹ naa lo ṣi wa lọwọ bayii, ibi gbogbo ti gomina ipinlẹ mi ba wa lemi naa maa wa.’

Leave a Reply