Wọn ti mu awọn ọmọ Naijiria yii ni UK, ayederu iwe-ẹri igbeyawo ni wọn n ṣe

Adewale Adeoye

Ẹwọn ọdun gbọọrọ ni wọn ju awọn ọmọ orileede Naijiria mẹrin kan si nilẹ  Gẹẹṣi bayii, ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe wọn n bawọn ọmọ orileede Naijiria ṣe ayederu iwe-ẹri igbeyawo ti wọn fi n gbe l’Oke Okun.

Awọn afurasi ọdaran naa ni: Abraham Alade Ọlarotimi Onifade, ẹni ọdun mọkanlelogoji, Abayọmi Aderinsọla Shodipọ, ẹni ọdun mejidinlogoji, Nọsimọt Mojisọla Gbadamọsi, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn ati Adekunle Kabir, ẹni ọdun mẹrinlelaaadọta.

ALAROYE gbọ pe lati ọdun 2019 si 2023 ni awọn afurasi ọdaran naa fi ṣiṣẹ to lodi sofin ọhun, ti wọn si ti ba ẹgbẹrun meji awọn ọmọ orileede Naijiria ṣe ayederu iwe-ẹri igbeyawo lati fi wọ orileede Gẹẹsi lọna aitọ.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, ni wọn ṣe idajọ wọn ni kootu kan ti wọn n pe ni Woolwich Crown Court, to wa nilẹ Gẹẹsi.

Agbegbe kan ti wọn n pe ni Gravesend, niluu Kent, lorileede Gẹẹsi ni Onifade n gbe, ilu Manchester, ni Shodipọ n gbe, nigba ti wọn ko darukọ adugbo tawọn meji yooku n gbe lasiko ti wọn foju wọn bale-ẹjọ naa laipẹ yii.

Ẹwọn ọdun mẹfa pẹlu iṣẹ aṣekara lọgba ẹwọn ni wọn ni ki wọn lọọ ṣe.

Leave a Reply