Wọn ti mu awọn eleyii o, ita gbangba ni wọn n ṣe igbọnsẹ si l’Ekoo

Adewale Adeoye

Mẹsan-an lara awọn araalu Eko ti wọn jẹ aleti lapa to jẹ pe ibi gan-an tijọba ni ki wọn ma ṣe igbọnsẹ si ni awọn maa n lo, lọwọ awọn agbofinro ti tẹ bayii. Ọsẹ yii si ni wọn maa foju gbogbo wọn pata bale-ẹjọ fohun to lodi sofin ipinlẹ Eko ti wọn ṣe.

ALAROYE gbọ pe ẹsun tawọn agbofinro ilu Eko fi kan awọn afurasi ọdaran naa ni pe wọn n ṣe igbọnsẹ nita gbangba laarin ilu Eko, leyii to lodi sofin, ti ijiya nla si wa fẹni to ba ṣe bẹẹ.

Kọmisana fun eto ayika nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Tokunbo Wahab, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, sọ pe lọjọ Ẹti, Furaidee, ọgbọnjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, lọwọ awọn oṣiṣẹ ajọ K.A.I, iyẹn ajọ to maa n mu awọn to ba huwa ibajẹ laarin ilu Eko tẹ awọn afurasi ọdaran naa lagbegbe Berger, niluu Eko, lasiko ti wọn n ṣe igbọnsẹ lọwọ nita gbangba.

Kọmiṣana nijọba Eko ko ni i fọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ awọn ọbayejẹ gbogbo ti wọn fẹẹ ba iṣẹ daadaa ti ijọba Eko n ṣe jẹ.

 

Leave a Reply