Hajiya Dada, iya aarẹ tẹlẹ, Musa Yar adua, ti ku o

Adewale Adeoye

Hajiya Dada, ti i ṣe iya aarẹ ilẹ wa tẹlẹ, Oloogbe Musa Yar adua, ti ku lọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ keji, oṣu Kẹsan-an yii, siluu Katsina, ti i ṣe ilu abinibi rẹ.

ALAROYE gbọ pe o ṣe diẹ  ti iya naa ti wa lori bẹẹdi ni ọsibitu ijọba kan ti wọn n pe ni ‘Federal Teaching Hospital’, to wa ni Katsina, aisan ọjọ ogbo lawọn dokita to n ṣetọju rẹ sọ pe o n ṣe e. Ko le sọrọ, bẹẹ ni ko le jẹun, ṣugbọn awọn dokita ṣe ohun ti wọn le ṣe lati du ẹmi rẹ pe ko ma bọ.

Oloogbe yii ni iya to bi aarẹ ilẹ wa nigba kan, Oloogbe Musa Yar adua, to ku ni nnkan bii ọdun mẹwaa sẹyin. Oun naa ni iya Senetọ Abdul Aziz Musa Yar adua, to wa nileegbimọ aṣofin agba ilẹ wa l’Abuja bayii.

Oloogbe Hajiya Dada yii ni iyawo akọkọ ti ọkọ rẹ, Oloogbe Yar adua fẹ. Ọkunrin naa jẹ jẹ ọkan pataki lara awọn oloṣelu ilẹ Hausa, ati lorileede Naijiria, ti ko sẹni to le fọwọ rọ ọ sẹyin. O ti figba kan jẹ minisita l’Ekoo, lasiko ijọba akọkọ ‘First Republic’.

Latigba to ti ku lawọn eeyan jankan-jankan ti n da lọ sile rẹ lati lọọ ba awọn ẹbi rẹ kẹdun iku iya agba naa. Lara awọn oloṣelu ilẹ Hausa ti wọn ti lọ sile oloogbe naa ni igbakeji aarẹ orileede yii tẹlẹ, Alhaji Atiku Abubarkar, atawọn eeyan jankan-jankan mi-in.

Ẹni ọdun mọkanlelọgọrun-un ni iya to ku ọhun.Awon ẹbi lawọn maa too sọ bi ayẹyẹ eto isinku oloogbe naa ṣe maa lọ laipẹ yii.

Leave a Reply