Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Gbogbo awọn to wa nibi ti ọmọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlogun kan, Phillip Emmanuel, ti n ka boroboro ni olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, ni wọn ya ẹnu wọn ti wọn ko le pa a de nigba ti wọn gbọ ọna ika ti ọmọ bibi ipinlẹ Edo ọhun ati ojugba rẹ kan fi ṣeku pa ọga wọn, iyẹn Abilekọ Adene Iyabọde Deborah, ẹni ti wọn pa nipakupa mọ’nu yara rẹ loju ọna Ọda, l’Akurẹ.
ALAROYE gbọ pe ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keje, ọdun 2024 yii, Emmanuel ati ẹnikan torukọ tiẹ n jẹ Precious, pa Abilekọ Adene, to jẹ ọga wọn.
Ṣe ni wọn gun obinrin naa lọbẹ ṣakaṣaka ni gbogbo ara, ti wọn si tun gbiyanju lati dana sun oku rẹ nigba ti wọn pa a tan.
Lẹyin eyi lawọn mejeeji ji kaadi ATM ọga wọn, ti wọn si lọọ gba ẹgbẹrun lọna ọgọta Naira ti wọn ba ninu asunwọn banki rẹ ki olukuluku wọn too ba ẹsẹ rẹ sọrọ.
Diẹ ninu alaye ti Emmanuel ṣe fun wa ree lasiko ti Alaroye n fọrọ wa a lẹnu wo lori ipa to ko lori bi wọn ṣe pa ọga rẹ.
“Nnkan bii oṣu kan sẹyin lawọn ọlọpaa mu mi lori ẹsun pe mo mọ nipa iku ọga wa lẹyin oṣu marun-un to ti gba mi ṣiṣẹ gẹgẹ bii ọmọọdọ rẹ.
Ki i ṣe ifẹ inu mi lati lọwọ ninu iku rẹ, nitori mi o paayan ri, ẹni to gba gẹgẹ bii awakọ ni nnkan bii ọsẹ meji ṣaaju iṣẹlẹ naa, iyẹn Precious, lo ba mi sọrọ pe ka pa a.
‘’Precious ni oun n gbọ ti ẹnikan n ba ọga wa sọrọ lori aago pe oun fẹẹ san owo kan to to bii ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹjọ Naira (#150,000) sinu asunwọn banki rẹ, idi ree to fi ni ka jumọ pa a, ka le lanfaani lati gba owo ọhun jade.
Ọpọ igba ni ọga wa ti maa n fun Precious ni kaadi ATM rẹ lati lọọ ba a gbowo wa ni banki, eyi lo fun un lanfaani lati mọ nọmba aṣiri kaadi naa.
‘’Lọjọ Abamẹta, Satide, ta a fẹẹ ṣiṣẹ ibi yii, emi ni ọga wa kọkọ pe lati ba a fọ aṣọ pẹlu bo ṣe lo rẹ oun diẹ lọjọ naa. Mi o ti i bẹrẹ si i fọ awọn aṣọ wọnyi ti Precious fi sare de, to ni oun fẹẹ ran an lọwọ lati fọ awọn aṣọ naa.
‘’Lẹyin eyi ni Precious fun mi ni ọti lile kan mu, to si fa ada yọ pe ṣiṣa loun maa ṣa mi pa ti mo ba fi kọ ja lati fọwọsowọpọ pẹlu oun lori ati pa ọga wa.
‘’Oun gan-an lo fipa fa mi wọnu yara ibi to sun si, to si ni ki n maa ṣa a ladaa to wa lọwọ mi, bi mo ṣe n ṣa ọga wa ladaa mọ ori bẹẹdi ni mo n sunkun, ṣugbọn mi o gbọdọ dawọ duro.
‘’Precious lo lọọ gba ẹgbẹrun lọna ọgọta Naira to wa ninu asunwọn rẹ, ninu eyi to ti fun emi ni ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira ki n too sa lọ si Idanre.
‘’Ibẹ ni mo tawọn ọlọpaa fi pe mi lẹyin ọjọ kẹrin lati waa sọ ohun ti mo mọ lori ọrọ bi wọn ṣe pa madaamu. Wọn kọkọ ni ki n maa lọ lọjọ akọkọ ti mo lọ sọdọ wọn, lẹyin-o-rẹyin ni wọn tun pada pe mi, wọn ni iwadii awọn fidi rẹ mulẹ pe ajọṣepọ kan wa laarin emi ati Precious ti awọn ṣi n wa lori iku ọga wa. Latigba naa ni mo ti wa ninu atimọle wọn”.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abayọmi Ọladipọ, ṣalaye pe awọn araadugbo kan ni wọn waa ta awọn ọlọpaa lolobo lẹyin ti wọn gbọ oorun buruku kan to n jade lati inu ile Abilekọ Adene.
Nigba to n gba awọn araalu nimọran, ọga ọlọpaa ọhun rọ awọn eeyan lati kiyesara lasiko ti wọn ba n gba ipe tabi sọrọ ni gbangba lori ọrọ owo.