Ijọba ipinlẹ Ogun bẹrẹ iforukọsilẹ fun awọn ọmọde fun eto ẹkọ ọfẹ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Yatọ si pe ijọba ipinlẹ Ogun ti sọ eto ẹkọ dọ̀fẹ́ fun iwe alakọọbẹrẹ, gbogbo ọna ni Gomina ipinlẹ naa, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, n san bayii lati ri i pe gbogbo awọn ọmọde nipinlẹ naa ni wọn janfaani eto ẹkọ to ye kooro.

Ni bayii, wọn ti bẹrẹ eto iforukọsilẹ awọn ọmọde fun eto ẹkọ-ọfẹ lati ipele jẹle-o-sinmi titi dopin iwe alakọọbẹrẹ.

Bakan naa lawọn alakooso eto ẹkọ nipinlẹ naa ti bẹrẹ si i kaakiri awọn ọja atawọn ibudokọ lawọn ilu nla nla bii Abẹokuta, Ṣagamu, Ijẹbu-Ode ati Ilaro, nipinlẹ naa

lati maa kede eto ẹkọ-ọfẹ ọhun.

Bẹẹ ni wọn n la awọn eeyan lọyẹ lori ọna ti wọn yoo gba janfaani eto naa ati bi anfaani ọhun ko ṣe ni i fo ẹnikẹni ru.

Nigba to n sọrọ nibi eto ilanilọyẹ ọhun, Kọmiṣanna feto ẹkọ nipinlẹ Ogun, Ọjọgbọn Abayọmi Arigbabu, sọ pe gbogbo ohun eelo ikẹkọọ to wa lawọn ileewe to jẹ tijọba kaakiri ipinlẹ naa nijọba ti ṣatunṣe si lati mu ẹkọ rọrun fun awọn akẹkọọ atawọn olukọ to n kọ wọn.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “idi ta a ṣe n ṣeto ilanilọyẹ yii ni lati jẹ ki ẹyin araalu mọ pe gbogbo ọmọde to jẹ olugbe ipinlẹ Ogun patapata, ijọba fẹ ki wọn janfaani eto ẹkọ to ye kooro lai yọ ẹnikẹni silẹ, bẹẹ ijọba ti sọ ẹkọ yii dọfẹ.

“A rọ awọn obi ati alagbatọ lati bẹrẹ si i lọọ fi orukọ awọn ọmọ wọn silẹ fun ṣaa eto ẹkọ ọdun 2024 si ọdun 2025, nileewe alakọọbẹrẹ to ba sun mọ wọn ju lọ, bẹrẹ lati aago mẹsan-an aarọ si aago kan ọsan ọjọ Aje, Mọnde, (ọjọ kẹsan-an, si ọjọ Ẹti, Furaidee (ọjọ kẹtala, oṣu kẹsan-an, ọdun 2024 yii).

“Ijọba ti ṣatunṣe si gbogbo ileewe alakọọbẹrẹ to wa nipinlẹ yii, a ti pese awọn yara ikẹkọọ ati yara fun ayẹwo imọ sayẹnsi tuntun pẹlu awọn aga ati gbogbo ohun eelo ikẹkọọ to yẹ fun ẹkọ tó lè mú ọjọ iwájú awọn ọmọ daa”.

Ninu ọrọ tiẹ, Akọwe agba fun ileeṣẹ eto ẹkọ nipinlẹ Ogun, Abilekọ Oluwatosin Ọlọkọ, gba awọn obi nimọran lati ni suuru ki awọn ọmọ wọn dagba to bo ṣe yẹ ki wọn dagba ko too di pe wọn fi wọn sileewe, to fi jẹ pe wọn yoo ti to ileewe giga a lọ nigba ti wọn yoo ba fi pari iwe girama.

Bakan naa l’Ọmọwe Mikail Lawal, ti i ṣe akọwe agba igbimọ eto ẹkọ kari aye (Universal Basic Education Board), nipinlẹ Ogun, gba awọn obi ati alagbatọ niyanju lati fi ẹkọ ọmọluabi kọ awọn ọmọ wọn ninu ile, ki wọn si jẹ awokọṣe rere fun awọn ọmọ naa.

Leave a Reply