Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ẹgbẹ awakọ, National Union of Road Transport Workers (NURTW) ẹka ti ipinlẹ Ọṣun, ti rawọ ẹbẹ si Gomina Ademọla Adeleke lati gbẹsẹ kuro lori aṣẹ to fi fofin de iṣẹ ẹgbẹ naa nipinlẹ Ọṣun.
Lasiko ipade kan ti ẹgbẹ naa ṣe niluu Oṣogbo laipẹ yii, ni Adele alaga wọn, Alhaji Kazeem Oyewale, ti sọ pe bi awọn ọmọ ẹgbẹ naa ṣe wa nile lati ọdun 2022 lai riṣẹ kankan ṣe n ṣe akoba nla fun idile wọn.
Gẹgẹ bo ṣe wi, ebi ọgajafọwọmẹkẹ lo n doju kọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa, bẹẹ ni ọpọ wọn ko lanfaani lati ran awọn ọmọ wọn nileewe mọ nitori ko si owo lọwọ wọn.
Tẹ o ba gbagbe, ipari ọdun 2022 ni Gomina Ademọla Adeleke fofin de ẹgbẹ awakọ NURTW nipinlẹ Ọṣun, tijọba si ṣagbekalẹ Park Management nigba naa.
Oyewale ṣalaye pe awọn ti wọn jẹ Park Management ko faaye gba awọn ti wọn mọ si NURTW lati fi mọto wọn ṣiṣẹ nibikibi nipinlẹ Ọṣun.
O ni ninu itan, ẹgbẹ NURTW l’Ọṣun, jẹ eyi ti ko ni wahala tabi jagidijagan rara, bẹẹ ni ibaṣepọ to dan mọran wa laarin awọn ọmọ ẹgbẹ kaakiri.
Oyewale sọ siwaju pe ọmọ iya kan naa lo yẹ ki Management Park ati NURTW jẹ, ṣugbọn pupọ iwa ti awọn tijọba gbe kalẹ bayii n hu lo jẹ eyi to le da omi alaafia ipinlẹ Ọṣun ru.
O rawọ ẹbẹ si Adeleke, ẹni to ṣapejuwe gẹgẹ bii olufẹ alaafia, lati ṣiju aanu wo awọn ọmọ ẹgbẹ NURTW, ki awọn naa le lanfaani lati ṣiṣẹ aje wọn nipinlẹ Ọṣun.