Jọkẹ Amọri
Ni ayajọ ọdun kan ti onkọrin ilẹ wa to ku lojiji nni, Ilerioluwa Alọba, ṣalaisi, iyawo to bimọ fun un, Wumi Alọba, ti kọ ọrọ idaro nipa ọkọ rẹ yii lati fi ṣami ọdun kan ti ọmọkunrin naa kuro loke eepẹ.
Ninu ọrọ to kọ naa lo ti sọ pe, ‘’Ilerioluwa, ọkọ igba ewe mi. O ti pe ọdun kan lonii- ọdun kan to o fi emi ati Liam silẹ sinu aye yii. O jẹ ohun to le fun mi gidigidi. Mo ṣafẹẹri rẹ lọpọlọpọ. Liam paapaa ṣafẹẹri rẹ. O wu mi bii ko o wa nibi lati ri i; o o ba jẹ baba to ṣe e mu yangan fun un. Mi o le ṣalaye bi mo ṣe tun wa laaye di akoko yii.
‘’Ọlọrun o, niṣe lo n ṣe mi bii ki o wa nibi fun wa lojoojumọ, ni gbogbo iṣẹju. Iku rẹ mu inira ti ko ṣee ṣalaye wa fun mi, ṣugbọn o tun tun mi ṣe, nitori mo ti kọ ẹkọ to pọ lọpọlọpọ, bẹẹ ni mo si tun n kẹkọọ lọwọlọwọ. Ko si bi ara mi ṣe le ṣe daadaa pẹlu aisi nibi rẹ, o n ṣẹ agbari mi bakanbakan. Ni gbogbo igba ni mo si n ronu bii pe ala ni mo n la, ati pe ma a ji loju oorun, ṣugbọn ọdun kan ti kọja to ti papoda, mi o ti i bọ ninu ala yii. Ọkọ mi, ọpọlọpọ eto la ni lọkan papọ, bẹẹ niwọ paapaa ni awọn ohun daadaa to o fẹẹ ṣe fun ọmọ araye. O dun mi de pinpin ọkan pe gbogbo ala rere ta a ni lọkan, gbogbo ohun gbogbo to o ṣiṣẹ karakara fun, lo ti lọ pẹlu rẹ.
‘’Mo fẹ ko o mọ pe emi ati Liam ṣi dirọ mọ okun ati ifẹ to o fun wa. Lojoojumọ ni mo n ri ara rẹ ninu mi, iwa daadaa rẹ, bi o ṣe maa n rẹrin-in, ẹmi rẹ. Mo ṣeleri lati ṣetọju ọmọ wa pẹlu ifẹ ati itọju ti iwọ paapaa iba fun un, bẹẹ ni ma a si pa iranti rẹ mọ ni gbogbo igbesẹ rẹ ninu aye
‘’Ṣugbọn lonii, mo yan lati ṣajọyọ rẹ. Lonii, mo yan lati ṣajọyọ ohun to o ti ṣe silẹ. Lonii, mo yan lati fi ogo fun Ọlọrun pe o fi ẹ ṣẹ ibukun fun mi, Ilerioluwa. Lonii, mo yan lati dupẹ fun ẹbun Liam, to jẹ ẹwa fun eeru wa.
Ifẹ mi, mo gbadura fun ọkan rẹ lonii. Mo gbadura pe ki Ọlọrun dari gbogbo aṣiṣe rẹ ji ẹ, ki o si ki ọ kaabọ si apa ọtun rẹ. Mo gbagbọ pe ajọyọ nla ni gbogbo igba ni fun ọ nibi to o wa. Mo nifẹẹ rẹ gidigidi. Mo dupẹ fun Liam-Mo n dupẹ titi laelae fun ẹbun ọmọ naa. Maa fo loke pẹlu awọn angẹli, ifẹ aye mi’’.
Bayii ni Wumi kọ ọrọ iwuri nipa ọkọ rẹ.
Bẹ o ba gbagbe, ọjọ kejila, oṣu Kẹsan-an, ọdun to kọja ni ariwo gba ilu kan pe ọmọkunrin to lẹbun orin daadaa naa ku, ti ariyanjiyan loriṣiirisii si waye lori iku rẹ.
Nigba ti ọrọ iku rẹ si fẹẹ dariwo lawọn ọlọpaa lọọ hu oku rẹ, pẹlu ileri lati ṣe ayẹwo, ki wọn si mọ iru iku to pa a.
Lasiko naa ni awọn ọlọpaa bẹrẹ iwadii, ti wọn si mu ọnkọrin to gbajumọ daadaa nni, Azeez Fashọla, Sam Larry atawọn mi-in ti wọn ni wọn lọwọ ninu iku rẹ.
Ṣugbọn titi di ba a ṣe n sọ yii, oku ọmọkunrin olorin tawọn eeyan fẹran daadaa naa wa ni mọṣuari, awọn mọlẹbi rẹ si wa lẹnu iwadii iku to pa a gan-an.