Jọkẹ Amọri
Laipẹ yii ni ALAROYE gbe iroyin kan nipa arẹwa oṣere ilẹ wa nni, Bisọla Badmus, lori ipenija aisan ti oṣere naa n koju, ati bi awọn oṣere kan ṣe ṣabẹwo si i, ti wọn si fun un lẹbun, nibi to ti bu sẹkun gbaragada.
Oṣere ilẹ wa to maa n ṣabẹwo sawọn oṣere ti wọn ba ni ipenija kan tabi omi-in nni, Kunle Afod, ti ṣabẹwo si oṣere to dudu daadaa naa nile ẹ.
Lasiko abẹwo naa ni Bisọla ṣalaye bi aisan to n ṣe e naa ṣe waye ati bo ṣe n bo o fun awọn eeyan lati nnkan bii ọdun mẹta sẹyin.
Oṣere naa ṣalaye pe, ‘’Lati bii ọdun mẹta sẹyin ni aisan yẹn, iyẹn awọn iṣan kan to maa n ṣu pọ sitosi ọpọlọ, ti ki i jẹ ko ṣiṣe daadaa, eyi ti awọn oloyinbo n pe ni ‘brain tumour’.
‘’Mo n ṣe e diẹdiẹ, nigba to waa pe ọdun meji, mi o le sọ nnkan kan mọ, ti mo ba ri ẹ gan-an, mi o le da ẹ mọ. Mo n lo oogun ṣa, oogun yẹn lo ran mi lọwọ, o ti n better.’’
Nigba to n ṣalaye ohun to maa n fa iru aisan bẹẹ fun Kunle Afod, o ni beeyan ba n ronu ju lo maa n ni iru aisan yii.
Nigba ti oṣerekunrin yii n beere lọwọ Bisọla boya aisan naa ko nilo ko ṣiṣẹ abẹ, oṣere naa sọ pe ki i ṣe ọrọ iṣẹ abẹ, oogun ni oun maa n lo. Ati pe ẹgbẹrun lọna ogun meje ataabọ, (150, 000) ni oun maa n ra awọn oogun naa, eyi to maa n gba a to oṣu kan lati lo.
Kunle Afod waa gba a niyanju lati maa sọrọ sita, o ni ọpọ awọn eeyan ni wọn ti pe oun, ti wọn si ṣetan ati ran an lọwọ. Ẹkun ni Bisọla tun bu si nigba ti Kunle Afod ko ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira tawọn kan fi ranṣẹ si i fun un.
Bẹẹ lo rọ awọn oṣere, awọn ololufẹ Bisọla lati dide iranlọwọ si i.
Nigba to n sọrọ, Bisọla Badmus dupẹ lọwọ awọn oṣere tiata ti wọn ti ran an lọwọ, awọn ololufẹ rẹ, atawọn afẹnifẹre.
Adura lawọn eeyan n gba fun oṣere to rẹwa daadaa naa pe ki Ọlọrun fun un lalaafia. Bẹẹ lawọn kan ti gba a niyanju pe ko ma maa gba ipe pupọ, ati pe to ba fẹẹ gba ipe, eti osi rẹ ni ko maa fi gba a ti ko ba le gbe e si sipika.