Monisọla Saka
Ileeṣẹ epo rọbi nilẹ wa, Nigerian National Petroleum Company (NNPCL), ti kede iye ti wọn yoo maa ta epo bẹntiroolu ti wọn ra nibudo ifọpo Dangote, kaakiri ilẹ Naijiria bayii.
Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, wọn ni ofin ileeṣẹ epo rọbi, iyẹn Petroleum Industrial Act (PIA), ko fun ijọba laaye lati paṣẹ iye ti wọn yoo maa ta epo, bi ko ṣe ajọsọ ọrọ laarin ileeṣẹ mejeeji to fẹẹ ta, to si fẹẹ ra a.
Ninu atẹjade ti wọn fi sita yii ni wọn ti ni, “Ileeṣẹ NNPC n kede bayii pe owo dọla lawọn yoo fi sanwo fun ileeṣẹ ifọpo Dangote, fun ọja ti wọn ra ninu oṣu Kẹsan-an, ọdun 2024. Ati pe o di inu oṣu Kẹwaa, ọdun yii, ki a too maa fi owo Naira ṣe katakara pẹlu wọn.
Bakan naa la n sọ ọ di mimọ pe ti ọrọ iye ti wọn fẹẹ maa ta epo yii ba mu họhuhọhu dani, yoo daa ki ileeṣẹ Dangote dinwo diẹ, leyii ti a oo pin si ori ọja ti a n ta si aarin ilu”.
Nigba ti wọn n sọ iye ti wọn yoo maa ta lita epo Dangote nipinlẹ kọọkan gẹgẹ bi iye ti wọn ra a loṣu Kẹsan-an, ọdun yii, ileeṣẹ NNPC ni ọgọrun-un mẹsan-an Naira ataabọ o le ṣenji diẹ (950.22), ni nipinlẹ Eko, ọgọrun-un mẹsan-an ati ọgọta Naira (960.22) ni nipinlẹ Ọyọ, Ẹgbẹrun kan din ogun Naira (980.22) ni nipinlẹ Rivers, Ẹgbẹrun kan din Naira mẹjọ (992.22) ni l’Abuja, ẹgbẹrun kan din Naira kan (999.22) ni nipinlẹ Kaduna, Kano ati Sokoto, nigba ti ti ipinlẹ Borno yoo jẹ ẹgbẹrun kan ati Naira mọkandinlogun (1.019).
Bakan naa ni wọn ṣalaye pe ẹẹdẹgbaarun din Naira meji (898.78), ni wọn ra jala epo kan jade lati ileeṣẹ ifọpo Dangote, nitori ẹ lo fi jẹ pe ida mẹẹẹdogun ni wọn yọ lori iye ti wọn ta a nipinlẹ Eko.
Ṣaaju akoko yii ni NNPC ti fi awọn ọmọ Naijiria lọkan balẹ pe iṣoro airi epo ra ati bi awọn eeyan ṣe n figba gbogbo to nile epo yoo dohun igbagbe laipẹ ọjọ, nitori bi wọn ṣe fẹẹ bẹrẹ si i maa ra epo lati ileeṣẹ Dangote lati ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu yii.
Wọn ṣalaye siwaju si i pe ki i ṣe ileeṣẹ Dangote tabi NNPC ni yoo sọ iye ti wọn yoo maa ta epo, bi ko ṣe bi ọja ba ṣe ri.
Ọgbẹni Dapọ Oluṣẹgun, ti i ṣe igbakeji ọga NNPC, naa fagi le awuyewuye to n lọ pe ileeṣẹ wọn lo bẹgi dina bi ileeṣẹ ifọpo Dangote ko ṣe bẹrẹ loju ọjọ.
O ni ọrọ ri bẹẹ nitori pe eto wa lori bi wọn ṣe n gba epo jade lati ibudo ifọpo, ati pe o ṣee ṣe fun awọn ile epo to ba wa nipinlẹ Eko lati ri ọja gba loojọ, amọ ti ko le ṣee ṣe fawọn to ba wa lọna jinjin.
Nigba to n sọrọ lori idi tijọba ko fi le da si iye ti wọn yoo maa ta epo, o ni ọrọ ileeṣẹ NNPC ko yatọ si ileeṣẹ oko-owo mi-in.
“Mo le sọ fun yin pe ko si aidaa kankan nibẹ. Gbogbo ohun to n ṣẹlẹ yii lo wa ni ibamu pẹlu ofin ati alakalẹ eto ti ileeṣẹ mejeeji tọwọ bọ, bo si ṣe yẹ ki oko-owo maa lọ niyẹn’’.
O nitori bẹẹ lo ṣe jẹ pe ọrọ iye ti wọn yoo maa ta epo ko si lọwọ ileeṣẹ NNPC tabi ileeṣẹ ifọpo Dangote, bi ọja ba ṣe wa, ni yoo sọ iye tawọn yoo maa ta a.