Adewale Adeoye
Olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, ti ṣabẹwo siluu Maiduguri, nipinlẹ Borno, lati wo bi ọrọ omiyale ṣe ba dukia awọn araalu naa jẹ. Bakan naa lo ṣeleri fun awọn olugbe ibẹ pe ijọba apapọ maa dide iranlọwọ fawọn ti omi ba dukia wọn jẹ laipẹ yii.
Ọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, ni Aarẹ lọ sibẹ lati ba wọn kẹdun bi arọọrọda ojo kan ṣe ba gbogbo ilu naa jẹ patapata.
Lara awọn eeyan jankan-jankan ti wọn pade Aarẹ Tinubu lasiko to wa siluu naa ni: Gomina ipinlẹ naa, Ọgbẹni Babagana Zulum, Emir ilu Borno, Alhaji Umar Ibn Garbai El-Kanemi, atawọn eeyan jankan-jankan mi-in.
Gomina ipinlẹ naa waa rawọ ẹbẹ si Tinubu pe ko gbiyanju lati ba wọn tun daamu to bajẹ, eyi to ṣokunfa iṣẹlẹ omiyale naa ṣe lasiko, ki iru iṣẹlẹ ibanujẹ bẹẹ ma baa waye mọ lọjọ iwaju.
Bakan naa lo dupẹ lọwọ Aarẹ lori awọn igbesẹ gidi to ti gbe fun ipinlẹ naa latigba ti ọrọ omiyale ọhun ti bẹrẹ.
Bẹ o ba gbagbe, lati nnkan bii ọsẹ kan sẹyin bayii ni ọrọ omiyale naa ti ṣẹlẹ nipinlẹ Borno, to si ti ba ọpọ dukia awọn araalu naa jẹ gidigidi.
Ajọ kan to n ri sọrọ iṣẹlẹ pajawiri laarin ilu ‘National Emergency Management Agency (NEMA), ti ni ida aadọrin ilu naa lomi ti bo mọlẹ, eyi to ja si pe nnkan tọrọ omiyale naa ti bajẹ kọja sisọ.