Jọkẹ Amọri
Gomina ipinlẹ Kogi tẹlẹ, Alaaji Yahya Bello, ti gbetiju ta, o si ti yọju si ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku nilẹ wa, EFCC, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu yii.
Nigba to n ṣalaye idi to fi gbe igbesẹ naa, Oludari eto iroyin rẹ, Ohiare Michael, ṣalaye pe, lẹyin ti Bello ti fikunlukun pẹlu awọn mọlẹbi rẹ, awọn agbẹjọro rẹ, atawọn alatilẹyin rẹ nidii oṣelu, ni gomina tẹlẹ naa fi gbe igbesẹ ọhun.
O ni, ‘’Gomina tẹlẹ naa jẹ ẹnikan to bọwọ fun ofin ati awọn alaṣẹ ilẹ wa, ṣugbọn ohun ti ko ti jẹ ko yọju lati ọjọ yii ni pe o fẹẹ gbe igbesẹ lati ri i pe wọn ko tẹ ẹtọ rẹ loju mọlẹ labẹ ofin.
‘’Wọn ti gbe ẹjọ rẹ lọ si ẹka eto idajọ to lẹtọọ lati gbọ ẹjọ naa, bẹẹ ni awọn agbẹjọro to jẹ aṣoju gomina tẹlẹ yii ko figba kankan kuna lati ṣoju rẹ nile-ẹjọ. O waa ṣẹ pataki fun gomina tẹlẹ naa bayii lati yọju si EFCC, ko si wẹ ara rẹ mọ kuro ninu awọn ẹsun ti wọn fi kan an, nitori ko ni ohunkohun lati fi pamọ taabi maa bẹru le lori.
‘’Gomina atijọ yii gbagbọ ninu iṣejọba Aarẹ Bọla Tinubu lati mu ọrọ aje wa padabọ sipo, bẹẹ lo ṣatilẹyin fun igbesẹ ijọba lati gbogun ti iwa ibajẹ nilẹ wa.
‘’O wa lakọsilẹ pe Yahya ni gomina akọkọ to kọkọ ṣe idasilẹ ajọ kan lati maa gbogun ti iwa ibajẹ nipinlẹ rẹ, ki wọn si ri i pe owo awọn eeyan ipinlẹ Kogi ṣiṣẹ fun awọn eeyan ibẹ.
‘’Ireti wa ni pe ajọ naa yoo gbe igbesẹ to yẹ labẹ ofin, ti wọn ko si ni i tẹ ẹtọ gomina yii loju mọlẹ gẹgẹ bii ojulowo ọmọ orileede Naijiria’’.
Bẹ o ba gbagbe, o ti to ọjọ mẹta ti ajọ amunifọba nni, EFCC, ti fiwe pe gomina ipinlẹ Kogi tẹlẹ ọhun lati yọju si wọn lori awọn ẹsun ikowojẹ ati ṣiṣẹ owo awọn eeyan ipinlẹ Kogi baṣubaṣu nigba to wa nipo. Ṣugbọn niṣe ni ọkunrin naa n sa fun wọn, ko too ṣeṣẹ waa jọwọ ara rẹ silẹ fun ajọ naa bayii.