Ẹ yee maa fenu tabuku Naijiria lori ayelujara- Fagbemi

Monisọla Saka

Minisita feto idajọ lorilẹ-ede yii, Attorney General of the Federation (AGF), Lateef Fagbemi, ti jawe ikilọ fawọn oloṣelu ti wọn ko mọ ju ki wọn maa tabuku Naijiria lori ayelujara, o ni iru awọn eeyan bẹẹ ko yẹ nipo adari nilẹ yii.

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, lo sọrọ naa nipasẹ oludamọran rẹ pataki lori eto iroyin, Ọgbẹni Kamar Ogundele, to ṣoju ẹ nibi eto kan ti wọn pe ni Social Media Summit, niluu Abuja.

Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ pe, ọna lati mu orilẹ-ede Naijiria kuro ninu wahala ati oju kan ti wọn wa, lo jẹ Aarẹ Tinubu logun ju lọ.

O rọ awọn eeyan lati ma ṣi anfaani ayelujara lo, nipa sisọ ọrọ to le yẹpẹrẹ orilẹ-ede yii, ti o si le ko ba awọn gan alara.

O ni anfaani ori ayelujara pọ, bẹẹ si lo jẹ pe awọn ọdọ n lo o lati ṣafihan ẹbun wọn.

“Gbogbo wa la gbọdọ gbaruku ti ọna lati sọ ilẹ Naijiria di nla, lai wo ti ija keekeeke ti ko lẹsẹ nilẹ. Iṣẹ takuntakun ni Aarẹ Tinubu n ṣe lojuna ati le mu Naijiria kuro loju kan to wa.

“Gẹgẹ bi wọn ṣe maa n sọ pe wọn ki i gbagbe ohunkohun teeyan ba ṣe, tabi to sọ lori ayelujara, a gbọdọ maa ṣọ ọrọ ta a n sọ lẹnu jade. Gbe ọrọ naa wo daadaa, ko o to sọ ọ jade. Nitori ẹyin lohun, to ba ti ja bọ ko ṣee ko mọ.

“Ki ẹnikẹni ma ṣe ṣi anfaani pe a ni ẹtọ lati sọ ohun to wu wa lori ayelujara lo, lati maa tẹ ẹtọ ọmọlakeji loju mọlẹ, nitori o ti n wọpọ ju. A tun gbọdọ ṣọra nipa ohun ti a o maa sọ nipa orilẹ-ede wa”.

O sọrọ siwaju si i pe kawọn eeyan ma tori pe wọn ko si ninu ẹgbẹ oṣelu kan naa, tabi nitori anfaani ‘ọfẹ ni ohùn’ tijọba fun wọn, ki wọn waa fẹnu ba Naijiria loju awọn orilẹ-ede agbaye. O ni afi ọmọ Naijiria tabi adari ti ko nifẹẹ ilu ẹ, ni yoo ṣeru ẹ. Nitori bẹẹ lo ṣe ni awọn ti wọn n sọ ohun ti ko daa nipa Naijiria lati le yanju aawọ yoowu ti wọn le ni nipa oṣelu, ko yẹ ki wọn ni anfaani lati dari orilẹ-ede ọhun kan naa, nipele yoowu.

Leave a Reply