Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Bi iṣẹ kan ba wa ti ọmọkunrin kan, Wasiu Raji, fẹran lati maa ṣe, iṣẹ ole jija ni. Idi niyẹn ti ikọ So-Safe to mu un nibi to ti n ja ọkada gba lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹfa, oṣu keje, ṣe pe e ni ọdaran gbogbo igba. Wọn lawọn mọ ọn bii ẹni mowo nidii iṣẹ ọhun, ati pe o ṣẹṣẹ tẹwọn de nitori ole jija ni.
Ọ̀bẹ to tobi kan ati igi gbọọrọ kan bayi lawọn So-Safe to n gbogun ti iwa ọdaran nipinlẹ Ogun sọ pe awọn ka mọ Wasiu lọwọ to fi n dunkooko mọ ọlọkada kan, Ogundele Adeyẹmi.
Niṣe ni wọn ni Wasiu di oju ọna lọwọ ara ẹ, eyi to lodi sofin. Ọna inu igbo tawọn eeyan n gba kọja loju ọna Ihunbọ si Ita-Ẹgbẹ, nijọba ibilẹ Ipokia, ni adigunjale yii gbe igi di lati maa ja awọn to ba n kọja lole.
Adeyẹmi to gbe Ọkada rẹ kọja lasiko ti Wasiu gbegi di oju ọna lo ko si wahala, nitori Alukoro So-Safe, Maruf Yusuf, ṣalaye pe ọbẹ ati igi nla ni Wasiu yọ si i, to si ṣe bẹẹ gba ọkada naa lọwọ ẹ.
Ṣugbọn ọwọ palaba afurasi ole yii segi, awọn So-Safe rin sasiko, wọn si mu un. Nigba ti wọn woju rẹ daadaa ni wọn ri i pe Wasiu Raji tawọn ti mu ri fun ole jija naa tun ni.
Alukoro sọ pe ile onile lo wọ nigba tawọn kọkọ mu un, foonu mẹrin lo si ji nibẹ, ohun to gbe e de ẹwọn niyẹn, to si lo oṣu mẹfa nibẹ. Bo ṣe tun jade lo tun bẹrẹ si i gbegidina fawọn eeyan yii.
Wọn ti fa a le teṣan ọlọpaa Idiroko lọwọ pẹlu awọn nnkan ija ti wọn ba lọwọ ẹ, ati ọkada Adeyẹmi to fipa gba lọwọ iyẹn.