Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, ti fi da awọn oṣiṣẹ ipinlẹ naa loju pe igbesẹ ti bẹrẹ lati mọ ọna tijọba yoo gba lori amuṣẹ sisan owo-oṣu oṣiṣẹ to kere ju lọ, eleyii ti ijọba apapọ kede rẹ laipẹ yii.
Nigba to n sọrọ nibi ạṣekagba ayẹyẹ ikẹkọọpari (Convocation) ẹlẹẹkẹrinla iru ẹ ti Fasiti Ọṣun, eyi to waye lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, ni Adeleke ṣalaye pe iṣejọba oun ko fi ọwọ kekere mu ọrọ igbaye-gbadun awọn oṣiṣẹ rara.
O ni oun mọ pe oniruuru ipenija ni yiyọ ẹkunwo ori epo bẹntiroolu mu ba wọn, ṣugbọn iṣejọba oun ti n ṣiṣẹ lati le din inira yii ku lori awọn oṣiṣẹ ti wọn wa pẹlu ijọba ipinlẹ Ọṣun.
Adeleke tun gboṣuba fun awọn alakooso Fasiti Ọṣun, pẹlu bi wọn ko ṣe faaye gba ohunkohun to jọ mọ iyanṣẹlodi, o ni eleyii lo fa a ti ina ile-ẹkọ naa fi n jo geerege laarin awọn fasiti to ku.
O waa ke si awọn oṣiṣẹ fasiti naa lati yago fun ohun to ba le gbegidina ilọsiwaju ile-ẹkọ naa, nitori loorekoore lawọn alaṣẹ wọn n mu ọrọ igbe aye irọrun wọn lọkun-unkundun lọdọ ijọba.
Gẹgẹ bo ṣe wi, “Ijọba wa ti ṣatilẹyin fun fasiti yii lori kikọ awọn ibugbe ti wọn n ṣe nnkan lọjọọ si, Anatomy Complex, bakan naa la ti ṣeleri lati ṣe oju-ọna to kọja si ile-ẹkọ yii lati ọja Ṣaṣha.
“A ti san owo ajẹmọnu fawọn oṣiṣẹ, bẹẹ la tun fun wọn ni owo alawansi palietiifu, a si tun ti bẹrẹ igbesẹ lori sisan owo oṣu oṣiṣẹ to kere ju, iyẹn, (new minimum wage), tijọba ṣẹṣẹ fọwọ si.
‘Mo fẹ ki ẹyin oṣiṣẹ ni fasiti yii mọ pe awọn alakooso yin ko fi ọrọ yin ṣere rara, nitori naa, ko gbọdọ si ẹni ti yoo fa ọkọ itẹsiwaju ile-ẹkọ yii sẹyin”.
Ṣaaju ninu ọrọ rẹ, ọga agba Fasiti Ọṣun, Ọjọgbọn Clement Adébòóyè, gboriyin fun gbogbo awọn lamẹẹtọ ile-ẹkọ naa fun ifowọsowọpọ wọn to mu wọn ṣaseyọri ti ko lẹgbẹ.
Adebooye ke si awọn adari lorileede Naijiria lati tubọ mu ọrọ eto ẹkọ lọkun-unkundun, ki wọn nawo le e lori bii ti awọn ẹka to ku.
O ni pupọ lara awọn ipenija to n dojukọ orileede yii ni ẹkọ to yanrannti le yanju, nitori imọ sayẹnsi ati imọ-ẹrọ jinlẹ lọpọlọpọ.