Ṣeyi Tinubu fun awọn eeyan ipinlẹ Borno lowo ati ounjẹ

Monisọla Saka

Ṣeyi Tinubu, ti i ṣe ọmọ Aarẹ orilẹ-ede yii, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ti fun awọn eeyan ilu Maiduguri, ti omiyale ṣọṣẹ fun ni ẹẹdẹgbẹta miliọnu Naira atawọn ohun eelo amaradẹni mi-in.

Ẹgbọn, ọrẹ, atawọn alajọṣe ni wọn tẹle Ṣeyi lọ siluu Maiduguri lọjọ Ẹti, Furaidee, ogunjọ, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, nigba to gbe owo naa kalẹ lorukọ awọn yooku.

Ṣeyi ni igbesẹ akọkọ ni wiwa tawọn wa yoo jẹ lati din iṣoro awọn eeyan ti omiyale naa han leemọ ku.

Bẹẹ lo fi wọn lọkan balẹ pe iranwọ yoo maa wa titi ti ipinlẹ Borno, paapaa ju lọ Maiduguri, ti i ṣe olu ilu ibẹ yoo fi pada bọ sipo.

Lasiko to n sọrọ nile ijọba ipinlẹ Borno, ti gomina atawọn jankan-jankan ti gba oun atawọn eeyan ẹ lalejo, lo ti ni, “A wa nibi lonii, ki i ṣe gẹgẹ bii aṣoju awọn mọlẹbi wa nikan, amọ gẹgẹ bii agbarijọpọ awọn ọdọ Naijiria, lati mu ireti ati itura wa fawọn to nilo rẹ ju. Asiko to yẹ ka jọ duro atilẹyin ree, asiko oju aanu ati igbesẹ oju-ẹsẹ.

“Ilu Maiduguri ati ipinlẹ Borno lapapọ ni itan gidi. Akinkanju eeyan ni wọn. Pẹlu gbogbo wahala to ti n waye lati aimọye ọdun sẹyin, wọn ko yee ṣe ọkan akin, idi si niyi ti gbogbo wa ṣe gbọdọ gbaruku ti wọn pẹlu atilẹyin ati adura lasiko ti ijamba ṣe wọn yii”.

“Iyawo mi, Layal, lo mu aba yii wa, pẹlu ifọwọsowọpọ emi ati ajọ Noella Foundation, ẹgbọn mi, Yinka, awọn ọrẹ wa, ati aimọye ileeṣẹ aladaani, ni a sowọ pọ pẹlu lati ṣeto fawọn ti ijamba yii ṣọṣẹ fun”.

Yatọ si owo ti wọn fun wọn yii, wọn tun ko nẹẹti ẹfọn bii ẹgbẹrun mẹwaa, aṣọ ibora nla, foomu bẹẹdi, age ikirun, iro, ike ipọnmi, ẹni, ohun eelo nnkan alejo obinrin, atawọn nnkan ti wọn le fi fọ nnkan fun wọn.

Wọn tun ko oogun to le ni aadọta ẹgbẹrun fun gbogbo awọn tọrọ kan, agbalagba at’ọmọde ni wọn pese oogun iba, oogun to n dena ẹjẹ ruru, oogun itọ ṣuga, ara riro ati eyi to n dena kokoro aifojuri fun.

Ninu ọrọ idupẹ rẹ si Gomina Babagana Zulum, ti ipinlẹ Borno, lo ti ni, “Ma a tun fẹ lati dupẹ pataki lọwọ Gomina Zulum, fun iṣẹ takuntakun wọn gẹgẹ bii adari rere niru akoko yii, ati fun gbogbo eeyan to n ṣiṣẹ lai dawọ duro lati ri i daju pe awọn nnkan ta a ko wa yii de ọdọ gbogbo mọlẹbi to nilo rẹ julọ.

“Ọlọla ju lọ, ẹyin adari pataki, ati ẹyin eeyan takuntakun ipinlẹ Borno, niru akoko inira yii, ojuṣe gbogbo wa ni lati jọ la a kọja. Gbogbo awọn ohun eelo ilera ati ounjẹ ta a ko wa sibi lonii jẹ ọna kekere tiwa lati fi atilẹyin ati oju aanu wa han, nitori a mọ pe ko si iru iranwọ ti a fẹẹ ṣe to le rọpo ẹmi ati ile ti ijamba yii ko ipalara ba.

“Amọ to jẹ pe ero wa ni pe nnkan kekere ta a mu wa yii yoo mu itura ati idẹrun ba awọn alaini. Pẹlu ifọwọsowọpọ gbogbo wa, a le ṣe atunkọ ati iwosan, ti agbara rẹ ba wa. Awa ọdọ Naijiria duro ti ipinlẹ Borno, gbogbo wa ni ọrọ yii jọ kan, bẹẹ ni a n gbadura fun yin. Gẹgẹ bi Aarẹ Tinubu ṣe sọ lọjọ Aje ti wọn wa, ipinlẹ Borno yoo tun pada gberi”.

Gomina Zulum dupẹ lọwọ Ṣeyi atawọn eeyan ẹ, bẹẹ lo fi wọn lọkan balẹ pe awọn yoo pin gbogbo nnkan ti wọn ko wa fawọn to nilo rẹ.

 

Leave a Reply