Ori Fesibuuku ni Rodiat ti pade Najeem, ọjọ akọkọ ti wọn rira lo ja a lole

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Alakooso ẹṣọ Amọtẹkun nipinlẹ Ọṣun, Dokita Ọmọyẹle Isaac Adekunle, ti ke si awọn ọdọbinrin lati kiyesara pẹlu awọn ọkunrin ti wọn n pade lori ikanni ayelujara.

Lasiko ti Ọmọyẹle n ṣafihan ọkunrin kan, Najeemdeen Ṣọla Bankọle Adeyẹmi, ẹni ti wọn lo ji foonu ọmọbinrin kan, Rodiat Adenikẹ Abdulrasaq, ti wọn jọ pade lori Fesibuuku lo sọrọ naa.

Gẹgẹ bi Ọmọyẹle ṣe ṣalaye, ọsan ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2024, ni Rọdiat lọọ fi ohun ti oju rẹ ri lọwọ Najeem to awọn Amọtẹkun leti.

Rọdiat, ọmọ bibi ilu Ọṣogbo, ṣalaye pe ori Fesibuuku loun ati Najeem ti pade, o si ṣeleri lati waa wo oun lati ilu Eko to n gbe.

O ni bo ṣe de Oṣogbo, lo ni kawọn lọọ ṣe faaji nileetura kan to wa nitosi, nibẹ lo si ti raaye ji foonu Android oun lọ, ti oun ko si gburoo rẹ mọ.

Bayii ni awọn Amọtẹkun bẹrẹ si i wa ọmọkunrin yii, wọn si ri i nipasẹ foonu rẹ pe ilu Eko lo wa, Ni wọn ba f’ọgbọn tan an wa siluu Oṣogbo, nibi ti ọwọ ti tẹ ẹ lasiko to tun fẹẹ ji foonu ọmọbinrin mi-in.

Nigba ti ọwọ tẹ ẹ lo jẹwọ pe aimọye ọmọbinrin ni wọn ti ko sinu pampẹ oun lati ori ikanni Fesibuuku, foonu ọwọ wọn loun si maa n gba.

Ọmọyẹle ṣalaye pe awọn yoo fa ọkunrin ẹni aadọta ọdun naa le awọn ọlọpaa lọwọ fun itẹsiwaju iwadii, ki wọn le gbe e lọ sile-ẹjọ lati le jẹ ẹkọ fun awọn bii tiẹ.

 

Leave a Reply