Adewale Adeoye
Ọmọ orileede Naijiria kan, Ọgbẹni Omoyomo Christopher, ẹni aadọta ọdun, ni Adajọ ile-ẹjọ giga kan, Onidaajọ Jennifer P. Wilson, sọ sẹwọn niluu Pennsylvania, lorileede Amẹrika, fun iwa ọdaran to hu lorileede naa.
ALAROYE gbọ pe Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, ni adajọ yii ju u sẹwọn ọgọrun-un oṣu, ti wọn si tun sọ pe ko san miliọnu mejilelogun dọla pada sapo ijọba ilẹ naa ko too di pe o maa jade lọgba ẹwọn ti wọn ju u si.
Agbẹjọro ijọba Amẹrika, Ọgbẹni Gerard M Karam, to foju olujẹjọ bale-ẹjọ sọ f’adajọ pe lati ọdun 2013 ni Okoro ti n gbe lorileede Amẹrika, tijọba si ti fun un niwee igbeluu lati d’ọmọ oniluu, ṣugbọn to jẹ pe iṣẹ jibiti lilu ati Yahoo-Yahoo lo n ṣe pẹlu awọn ọrẹ rẹ kan ti wọn n gbe lorileede Canada bayii.
Laarin ọdun 2006 si 2010 lo fi lu awọn araalu naa ni jibiti owo nla nipasẹ pe a parọ gbowo lọwọ wọn pe oun maa ba wọn gbowo tawọn ẹbi wọn kan ni sinu banki lorileede Amẹrika jade. Lẹyin tawọn yẹn ba fowo ranṣẹ si i tan ni yoo ba kọju wọn soorun alẹ. Yatọ si eyi, afurasi ọdaran naa tun n lo ẹrọ kọmputa lati fi ṣe Yahoo-Yahoo fawọn oyinbo lorileede naa. Oriṣii ẹsun meji ni wọn fi kan an.
Nigba to maa ṣe idajọ rẹ, adajọ paṣẹ pe ki Okoro lọọ ṣẹwọn ọgọrun-un oṣu ninu ọgba ẹwọn pẹlu iṣẹ aṣekara lọgba ẹwọn ti wọn ba ju u si.