Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ọjọgbọn Ọlalekan Yinusa, ti sọ pe ẹni ti oye idagbasoke ilu ko ba ye nikan ni yoo sọ pe gomina ana l’Ọṣun, Alhaji Gboyega Oyetọla, to jẹ minisita fun ọrọ okoowo ati irinkerindo ọkọ lori omi, ko gbiyanju to nileeṣẹ naa.
Yinusa, ẹni to ti figba kan jẹ kọmiṣanna fun atupalẹ eto iṣuna nipinlẹ Ọṣun, lo ṣoju Oyetọla nibi eto owo-iranwọ ti Ẹnjinnia Kayọde Ṣowade maa n ṣe fun awọn eeyan ilu Mọdakẹkẹ.
O ni gbogbo awọn ti wọn n sọ pe ṣe ni ki Aarẹ Bọla Tinubu yọ ọ nipo minisita kan n sọrọ alailoye ni, nitori wọn ko jokoo lati woye oniruuru iṣẹ ribiribi ti Oyetọla ti ṣe nileeṣẹ tuntun ọhun.
Ọjọgbọn yii sọ siwaju pe Tinubu mọ pe ọlọpọlọ pipe, to jẹ akọṣẹmọṣẹ ni Oyetọla, idi niyẹn to ṣe fi i si ileeṣẹ tuntun, ti ẹnikẹni ko ti i tọwọ bọ ri, gbogbo aye lo si ri i bayii pe ko ja awọn ọmọ orileede yii kulẹ rara.
Eto naa, eleyii to jẹ ẹlẹẹkarun iru ẹ, ni Ṣowade gbe kalẹ fun awọn araalu, lai fi ti ẹya, ẹsin, tabi ẹgbẹ oṣelu ṣe, o si to ẹgbẹrun kan ati ọọdunrun eeyan ti wọn janfaani eto ọhun lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹwaa, ọdun yii.
Yinusa gboṣuba fun Ṣowade lori eto naa, o ni ko si inu ile ti owo-iranwọ naa wọ ti ara ko ni i tu wọn, o si tun ke si awọn ti ori ṣẹgi ọla fun lati ṣawokọṣe ọkunrin oloṣelu naa.
Ninu ọrọ rẹ, Ẹnijinnia Kayọde Ṣowade, sọ pe o kere tan, eeyan ẹgbẹrun mẹrin lo ti janfaani owo-iranwọ igbadegba naa, oun yoo si tẹsiwaju ninu rẹ titi di ọdun 2026.
O ṣalaye pe ẹkọ ti oun ri kọ lara Oyetọla lasiko to jẹ gomina ipinlẹ Ọṣun lo fun oun ni iwuri lati gbe eto naa kalẹ fun awọn eeyan ilu abinibi oun, Mọdakẹkẹ.
Ṣowade sọ siwaju pe eto naa, ti oun pe ni Oyetọla Hand of Fellowship, loun fi n dẹrin-in pẹẹkẹ awọn araalu lai fi ti ẹgbẹ oṣelu ṣe.
Bakan naa ni aṣaaju kan ninu ẹgbẹ APC, Oluọmọ Sunday Akere, sọ pe eto naa yoo tubọ mu ki awọn araalu mọ pe ẹgbẹ kan ṣoṣo to ni ifẹ wọn lọkan ni ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC.