Ọlọpaa n wa Ganiyu to figo gun ibatan rẹ pa l’Ekoo 

Adewale Adeoye

Titi di asiko ta a n koroyin yii jọ lawọn agbofinro ipinlẹ Eko ṣi n wa afurasi ọdaran kan, Ọgbẹni Ganiyu Ibrahim, to figo gun ibatan rẹ, Oloogbe Afeez Akeem, pa lọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹwaa, ọdun yii.

ALAROYE gbọ pe ọrọ kekere kan lo pada dija nla laarin afurasi ọdaran naa ati ibatan rẹ, kawọn araale ti wọn n gbe l’Ekoo si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, Ganiyu ti pa igo mọlẹ, o ti fi gun oloogbe naa nigbaaya, niyẹn ba ṣubu lulẹ gbalaja, to si n pokaka iku. Awọn araale ati iya afurasi ọdaran naa ni wọn sare gbe oloogbe lọ sileewosan ijọba to wa lagbegbe ibi ti wọn n gbe, ṣugbọn awọn dokita ni oku rẹ ni wọn gbe wa. Ọmọkunrin naa ti ku ko too de ọsibitu.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, S.P Benjamin Hundeyin, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, sọ pe iya afurasi ọdaran naa lo pada lọọ fiṣẹlẹ ọhun to awọn ọlọpaa leti pe ọmọ oun, Ganiyu, ni ija kekere kan pẹlu ibatan rẹ, lasiko naa lọrọ pada di ohun ti wọn n di mọ ara wọn nita gbangba, kawọn araale si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, Ganiyu ti fi afọku igo ọwọ rẹ gun oloogbe naa pa.

Alukoro ni awọn agbofinro ti lọ sibi iṣẹ̀ẹ ọhun, awọn si n wa afurasi ọdaran naa lati le fọwọ ofin mu un fohun to ṣe yii.

Leave a Reply