O ma ṣe o, oṣere tiata mi-in tun ku lojiji

Agbọ-sọgba-nu ni iku ọkan pataki ninu awọn oṣere ilẹ wa to maa n saaba kopa baba olowo ninu ere, to si tun maa n ṣe ọba ninu fiimu agbelewo Yoruba nni, Ayọbami Mudashir Ọlabiyi, ti gbogbo eeyan mọ si Bọbọ B, ṣi n jẹ fun ọpọ awọn ololufẹ rẹ, paapaa ju lọ ẹgbẹ awọn oṣere.

ALAROYE gb ọ pe ọsibitu ẹkọṣẹ iṣegun ijọba to wa nipinlẹ Ọyọ, iyẹn University College Hospital (UCH), ni ọkunrin naa dakẹ si l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu yii.

Wọn ni o ṣe diẹ to ti rẹ ọkunrin naa, to si n gba itọju nileewosan. Aisan naa si mu un lomi diẹ nitori wọn ni baba naa ko le sọrọ, bẹẹ ni ko le gbe apa ati ẹsẹ rẹ nibi to le de.

Ọpọ eeyan ni ko mọ pe Bọbọ B n ṣaisan, koda ti ki i baa ṣẹ aisan to da a gbalẹ ni, o yẹ ko wa loko ere kan ni niluu Ọyọ, ṣugbọn idubulẹ aisan to wa ko jẹ ko le darapọ mọ wọn.

Nigba to n fidi iku ọkan ninu wọn naa mule, Aarẹ ẹgbẹ awọn oṣere nipinlẹ Ọyọ, Yeye Bọsẹ Akinọla, sọ pe loootọ ni Ayọbami ti ku. Bẹẹ lo kẹdun pẹlu mọlẹbi rẹ ati ẹgbẹ oṣere lapapọ.

Oloogbe yii ti figba kan jẹ akọwe agba apapọ ẹgbẹ awọn onitiata, bakan naa lo ti ṣe gomina ẹgbẹ naa nipinlẹ Ọyọ ko too dagbere faye.

Ọpọ awọn oṣere ni wọn ti n daro iku ọkan ninu wọn to ku lojiji ọhun.

Leave a Reply